Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lefitiku 23:2-18 BIBELI MIMỌ (BM)

2. pé kí ó sọ fún àwọn eniyan Israẹli pé, “Àwọn àjọ̀dún tí èmi OLUWA yàn tí ó gbọdọ̀ kéde gẹ́gẹ́ bí ìpéjọ mímọ́ nìwọ̀nyí:

3. Ọjọ́ mẹfa ni kí ẹ fi ṣiṣẹ́, ṣugbọn ọjọ́ keje jẹ́ ọjọ́ ìsinmi tí ó lọ́wọ̀, ati ọjọ́ ìpéjọ mímọ́. Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan ní ọjọ́ náà, ọjọ́ ìsinmi ni fún OLUWA ní gbogbo ibùgbé yín.

4. Èyí ni àwọn àjọ̀dún ati àpèjọ tí OLUWA yàn, tí wọ́n gbọdọ̀ kéde, ní àkókò tí OLUWA yàn fún wọn.

5. “Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kẹrinla oṣù kinni ni kí ẹ máa ṣe àjọ ìrékọjá OLUWA.

6. Ní ọjọ́ kẹẹdogun oṣù kan náà sì ni àjọ àìwúkàrà OLUWA. Ọjọ́ meje gbáko ni ẹ gbọdọ̀ fi máa jẹ burẹdi tí kò ní ìwúkàrà.

7. Ní ọjọ́ kinni, ẹ níláti ní àpèjọ, ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ tí ó bá lágbára.

8. Ṣugbọn, ẹ óo máa rú ẹbọ sísun sí OLUWA fún ọjọ́ meje náà, ọjọ́ àpèjọ mímọ́ ni ọjọ́ keje yóo jẹ́, ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ tí ó lágbára.”

9. OLUWA tún rán Mose pé kí ó

10. sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ tí n óo fun yín, tí ẹ bá sì ń kórè nǹkan inú rẹ̀, ẹ níláti gbé ìtí ọkà kan lára àkọ́so oko yín tọ alufaa lọ.

11. Nígbà tí ó bá di ọjọ́ keji, lẹ́yìn ọjọ́ ìsinmi, alufaa yóo fi ìtí ọkà náà rú ẹbọ fífì níwájú OLUWA, kí ẹ lè jẹ́ ẹni ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ rẹ̀.

12. Ní ọjọ́ tí ẹ bá ń fi ìtí ọkà yín rú ẹbọ fífì, kí ẹ fi ọ̀dọ́ akọ aguntan ọlọ́dún kan, tí kò ní àbààwọ́n rú ẹbọ sísun sí OLUWA.

13. Ẹbọ ohun jíjẹ tí ẹ óo rú pẹlu rẹ̀ nìyí: ìdámárùn-ún ìwọ̀n efa ìyẹ̀fun tí wọ́n fi òróró pò, ẹ óo fi rú ẹbọ sísun olóòórùn dídùn sí OLUWA, kí ẹ sì fi idamẹrin ìwọ̀n hini ọtí waini rú ẹbọ ohun mímu pẹlu rẹ̀.

14. Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ burẹdi tabi ọkà, kì báà jẹ́ ọkà yíyan tabi tútù títí di ọjọ́ yìí, tí ẹ óo fi mú ẹbọ Ọlọrun yín wá, ìlànà ni èyí yóo jẹ́ fún ìrandíran yín, ní gbogbo ilẹ̀ yín.

15. “Ẹ óo ka ọ̀sẹ̀ meje, bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ keji ọjọ́ ìsinmi tí ẹ mú ìtí ọkà fún ẹbọ fífì wá fún OLUWA.

16. Ẹ óo ka aadọta ọjọ́ títí dé ọjọ́ keji ọjọ́ ìsinmi keje, lẹ́yìn náà, ẹ óo mú ẹbọ ohun jíjẹ tí ẹ fi ọkà titun ṣe wá fún OLUWA.

17. Ẹ óo mú burẹdi meji tí wọ́n fi ìdámárùn-ún ìwọ̀n efa ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára ṣe wá fún ẹbọ fífì; àwọn àkàrà náà yóo ní ìwúkàrà ninu, ẹ óo mú wọn tọ OLUWA wá gẹ́gẹ́ bí àkọ́so oko yín.

18. Ẹ óo mú ọ̀dọ́ aguntan meje ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan tí kò ní àbùkù lọ́wọ́, pẹlu ọ̀dọ́ akọ mààlúù kan ati àgbò meji, nígbà tí ẹ bá ń kó àwọn ìṣù àkàrà meji náà bọ̀. Àwọn ni ẹ óo fi rú ẹbọ sísun sí OLUWA; pẹlu ẹbọ ohun jíjẹ, ati ẹbọ ohun mímu, ẹbọ tí a fi iná sun, olóòórùn dídùn, tí OLUWA gbádùn ni.

Ka pipe ipin Lefitiku 23