Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lefitiku 22:20-31 BIBELI MIMỌ (BM)

20. Ẹ kò gbọdọ̀ fi ohunkohun tí ó bá ní àbààwọ́n rúbọ, nítorí pé, OLUWA kò ní tẹ́wọ́gbà á lọ́wọ́ yín.

21. Nígbà tí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ rú ẹbọ alaafia sí OLUWA láti san ẹ̀jẹ́, tabi fún ọrẹ àtinúwá; kì báà jẹ́ láti inú agbo mààlúù tabi láti inú agbo aguntan ni yóo ti mú ẹran ìrúbọ yìí, ó níláti jẹ́ pípé, kò gbọdọ̀ ní àbùkù kan lára, kí ẹbọ náà lè jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà.

22. Bí ẹran náà bá jẹ́ afọ́jú, tabi amúkùn-ún, tabi ẹran tí ó farapa, tabi tí ara rẹ̀ ń tú, tabi tí ó ní èkúkú, ẹ kò gbọdọ̀ fi wọ́n fún OLUWA, tabi kí ẹ fi wọ́n rú ẹbọ sísun lórí pẹpẹ sí OLUWA.

23. Bí apá tabi ẹsẹ̀ mààlúù tabi àgbò kan bá gùn ju ekeji lọ, ẹ lè mú un wá fún OLUWA gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ àtinúwá, ṣugbọn OLUWA kò ní tẹ́wọ́gbà wọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹran ìrúbọ láti fi san ẹ̀jẹ́.

24. Bí wọ́n bá tẹ ẹran kan lọ́dàá, tabi bí kóró abẹ́ rẹ̀ bá fọ́, tabi tí abẹ́ rẹ̀ fàya, tabi tí wọ́n la abẹ́ rẹ̀, tabi tí wọ́n ṣá a lọ́gbẹ́ ní abẹ́, ẹ kò gbọdọ̀ mú un wá fún OLUWA, tabi kí ẹ fi rúbọ ninu gbogbo ilẹ̀ yín.

25. “Bí ẹ bá gba irú ẹran bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ àlejò, ẹ kò gbọdọ̀ fi rú ẹbọ ohun jíjẹ sí èmi Ọlọrun yín. Níwọ̀n ìgbà tí àbùkù bá ti wà lára wọn, OLUWA kò ní tẹ́wọ́gba irú wọn lọ́wọ́ yín, nítorí àbùkù náà.”

26. OLUWA sọ fún Mose pé:

27. “Nígbà tí mààlúù, aguntan, tabi ewúrẹ́ bá bímọ, ẹ fi ọmọ náà sílẹ̀ pẹlu rẹ̀ fún ọjọ́ meje, láti ọjọ́ kẹjọ lọ ni ó tó lè jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún ẹbọ sísun sí OLUWA.

28. Ẹ kò gbọdọ̀ fi ìyá ẹran ati ọmọ rẹ̀ rúbọ ní ọjọ́ kan náà; kì báà jẹ́ mààlúù, tabi aguntan, tabi ewúrẹ́.

29. Nígbà tí ẹ bá sì ń rú ẹbọ ọpẹ́ sí OLUWA, ẹ gbọdọ̀ rú u ní ọ̀nà tí yóo fi jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà.

30. Ẹ níláti jẹ gbogbo rẹ̀ tán ní ọjọ́ kan náà, kò gbọdọ̀ kù di òwúrọ̀ ọjọ́ keji. Èmi ni OLUWA.

31. “Ẹ gbọdọ̀ ṣàkíyèsí òfin mi, kí ẹ sì máa pa wọ́n mọ́. Èmi ni OLUWA.

Ka pipe ipin Lefitiku 22