Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lefitiku 20:12-16 BIBELI MIMỌ (BM)

12. Bí ẹnikẹ́ni bá bá aya ọmọ rẹ̀ lòpọ̀, pípa ni kí wọ́n pa àwọn mejeeji; wọ́n ti hùwà ìbàjẹ́ láàrin ẹbí, ẹ̀jẹ̀ wọn yóo wà lórí ara wọn.

13. Bí ọkunrin kan bá bá ọkunrin ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ lòpọ̀ bí a ti ń bá obinrin lòpọ̀, àwọn mejeeji ti ṣe ohun ìríra; pípa ni kí wọ́n pa wọ́n, ẹ̀jẹ̀ wọn yóo wà lórí ara wọn.

14. Bí ẹnìkan bá fẹ́ iyawo, tí ó sì tún fẹ́ ìyá iyawo náà pẹlu, ìwà burúkú ni; sísun ni kí wọ́n sun wọ́n níná, ati ọkunrin ati àwọn obinrin mejeeji, kí ìwà burúkú má baà wà láàrin yín.

15. Bí ọkunrin kan bá bá ẹranko lòpọ̀, pípa ni kí ẹ pa òun ati ẹranko náà.

16. Bí obinrin bá tọ ẹranko lọ, tí ó sì tẹ́ ara rẹ̀ sílẹ̀ fún un láti bá a lòpọ̀, pípa ni kí ẹ pa òun ati ẹranko náà, ẹ̀jẹ̀ wọn yóo wà lórí ara wọn.

Ka pipe ipin Lefitiku 20