Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lefitiku 19:5-17 BIBELI MIMỌ (BM)

5. “Nígbà tí ẹ bá rú ẹbọ alaafia sí OLUWA, ẹ rú u ní ọ̀nà tí yóo fi jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà.

6. Ní ọjọ́ tí ẹ bá rú ẹbọ náà gan-an tabi ní ọjọ́ keji rẹ̀ ni ẹ gbọdọ̀ jẹ ohun tí ẹ fi rúbọ tán. Bí ohunkohun bá kù di ọjọ́ kẹta, sísun ni ẹ gbọdọ̀ dáná sun ún.

7. Bí ẹnikẹ́ni bá jẹ ẹ́ ní ọjọ́ kẹta, ohun ìríra ni, kò sì ní jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà mọ́.

8. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì jẹ ẹ́ yóo jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, nítorí pé, ó ti ba ohun mímọ́ OLUWA jẹ́, a óo yọ ọ́ kúrò láàrin àwọn eniyan rẹ̀.

9. “Nígbà tí o bá ń kórè oko rẹ, o kò gbọdọ̀ kórè títí kan ààlà. Lẹ́yìn tí o bá ti kórè tán, o kò gbọdọ̀ pada lọ tún kórè àwọn ohun tí o bá gbàgbé.

10. O kò gbọdọ̀ kórè gbogbo àjàrà rẹ tán patapata, o kò sì gbọdọ̀ ṣa àwọn èso tí ó bá rẹ̀ sílẹ̀ ninu ọgbà àjàrà rẹ, o níláti fi wọ́n sílẹ̀ fún àwọn talaka ati àwọn àlejò. Èmi ni OLUWA Ọlọrun rẹ.

11. “Ẹ kò gbọdọ̀ jalè, ẹ kò gbọdọ̀ fi ìwà ẹ̀tàn bá ara yín lò; ẹ kò sì gbọdọ̀ parọ́ fún ara yín.

12. Ẹ kò gbọdọ̀ fi orúkọ mi búra èké, kí ẹ má baà ba orúkọ Ọlọrun yín jẹ́. Èmi ni OLUWA.

13. “Ẹ kò gbọdọ̀ pọ́n aládùúgbò yín lójú tabi kí ẹ jà á lólè; owó iṣẹ́ tí alágbàṣe bá ba yín ṣe kò gbọdọ̀ di ọjọ́ keji lọ́wọ́ yín.

14. Ẹ kò gbọdọ̀ gbé adití ṣépè tabi kí ẹ gbé ohun ìdìgbòlù kalẹ̀ níwájú afọ́jú, ṣugbọn ẹ níláti bẹ̀rù Ọlọrun yín. Èmi ni OLUWA.

15. “Ẹ kò gbọdọ̀ dájọ́ èké, ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe ojuṣaaju sí talaka tabi ọlọ́rọ̀, ṣugbọn ẹ gbọdọ̀ máa dá ẹjọ́ àwọn aládùúgbò yín pẹlu òdodo.

16. Ẹ kò gbọdọ̀ máa ṣe òfófó káàkiri láàrin àwọn eniyan yín, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ kọ̀ láti jẹ́rìí aládùúgbò yín, bí ẹ̀rí yín bá lè gba ẹ̀mí rẹ̀ là. Èmi ni OLUWA.

17. “Ẹ kò gbọdọ̀ di arakunrin yín sinu, ṣugbọn ẹ gbọdọ̀ máa sọ àsọyé pẹlu aládùúgbò yín, kí ẹ má baà gbẹ̀ṣẹ̀ nítorí tirẹ̀.

Ka pipe ipin Lefitiku 19