Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lefitiku 17:10-16 BIBELI MIMỌ (BM)

10. “Bí ẹnikẹ́ni ninu àwọn ọmọ Israẹli tabi àlejò tí ń ṣe àtìpó láàrin wọn bá jẹ ẹ̀jẹ̀, èmi OLUWA yóo bínú sí olúwarẹ̀, n óo sì yọ ọ́ kúrò láàrin àwọn eniyan rẹ̀.

11. Nítorí pé, ninu ẹ̀jẹ̀ ni ẹ̀mí ohun alààyè gbogbo wà; mo sì ti fun yín, pé kí ẹ máa ta á sórí pẹpẹ, kí ẹ máa fi ṣe ètùtù fún ẹ̀mí yín; nítorí pé ẹ̀jẹ̀ níí ṣe ètùtù, nítorí ẹ̀mí tí ó wà ninu rẹ̀.

12. Nítorí rẹ̀ ni mo fi sọ fún ẹ̀yin ọmọ Israẹli pé, ẹnikẹ́ni ninu yín kò gbọdọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni àlejò tí ń ṣe àtìpó láàrin yín kò gbọdọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀.

13. “Ẹnikẹ́ni ninu àwọn ọmọ Israẹli, tabi àwọn àlejò tí ń ṣe àtìpó láàrin wọn tí ó bá lọ ṣe ọdẹ tí ó sì pa ẹran tabi ẹyẹ tí eniyan lè jẹ, ó níláti ro gbogbo ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀ kí ó sì wa erùpẹ̀ bò ó.

14. Nítorí pé, ninu ẹ̀jẹ̀ ni ẹ̀mí gbogbo ohun alààyè wà, nítorí náà ni mo fi sọ fún ẹ̀yin ọmọ Israẹli pé, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀ ẹ̀dá alààyè kankan, nítorí pé, ninu ẹ̀jẹ̀ ni ẹ̀mí ẹ̀dá alààyè gbogbo wà, ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ẹ́, a óo yọ ọ́ kúrò.

15. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì jẹ ohunkohun tí ó kú fúnra rẹ̀, tabi tí ẹranko burúkú fà ya, kí ẹni náà fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́, lẹ́yìn ìgbà náà ni yóo tó pada di mímọ́.

16. Ṣugbọn, tí kò bá fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, yóo jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.”

Ka pipe ipin Lefitiku 17