Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lefitiku 15:14-22 BIBELI MIMỌ (BM)

14. Nígbà tí ó bá di ọjọ́ kẹjọ, kí ó mú àdàbà meji, tabi ọmọ ẹyẹlé meji, kí ó wá siwaju OLUWA lẹ́nu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ, kí ó sì kó wọn fún alufaa.

15. Alufaa yóo fi wọ́n rúbọ: yóo fi ọ̀kan rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, yóo sì fi ekeji rú ẹbọ sísun. Yóo ṣe ètùtù fún ìwẹ̀nùmọ́ ọkunrin náà, níwájú OLUWA.

16. “Kí ọkunrin tí nǹkan ọkunrin rẹ̀ bá dà sí lára, kí ó wẹ gbogbo ara rẹ̀ láti òkè dé ilẹ̀, yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.

17. Gbogbo aṣọ ati awọ tí nǹkan ọkunrin náà bá dà sí gbọdọ̀ jẹ́ fífọ̀, kí ó sì jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.

18. Bí ọkunrin bá bá obinrin lòpọ̀, tí nǹkan ọkunrin sì jáde lára rẹ̀, kí àwọn mejeeji wẹ̀, kí wọ́n sì jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.

19. “Nígbà tí obinrin bá ń ṣe nǹkan oṣù rẹ̀, kí ó wà ní ipò àìmọ́ fún ọjọ́ meje. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì fi ara kàn án jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.

20. Ohunkohun tí ó bá dùbúlẹ̀ lé lórí, tabi tí ó jókòó lé lórí ní gbogbo àkókò àìmọ́ rẹ̀ yóo di aláìmọ́.

21. Kí ẹnikẹ́ni tí ó bá fara kan ibùsùn rẹ̀, fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀; yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.

22. Kí ẹnikẹ́ni tí ó bá fara kan ohunkohun tí ó fi jókòó, fọ aṣọ rẹ̀, kí ó wẹ̀; yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.

Ka pipe ipin Lefitiku 15