Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lefitiku 14:36-50 BIBELI MIMỌ (BM)

36. Kí alufaa pàṣẹ pé kí wọn kó gbogbo ohun tí ó wà ninu ilé náà jáde, kí ó tó lọ yẹ àrùn náà wò; kí ó má baà pe gbogbo ohun tí ó wà ninu ilé náà ní aláìmọ́; lẹ́yìn náà, kí alufaa lọ wo ilé náà.

37. Kí ó yẹ àrùn náà wò, bí ó bá jẹ́ pé lára ògiri ilé ni àrùn yìí wà, tí ibi tí ó wà lára ògiri náà dàbí àwọ̀ ewéko tabi tí ó pọ́n, tí ọ̀gangan ibẹ̀ sì jìn ju ara ògiri lọ.

38. Kí alufaa jáde kúrò ninu ilé náà, kí ó lọ síbi ìlẹ̀kùn, kí ó ti ìlẹ̀kùn ilé náà fún ọjọ́ meje.

39. Alufaa yóo pada wá ní ọjọ́ keje láti yẹ ilé náà wò. Bí àrùn bá ti tàn káàkiri lára ògiri ilé náà,

40. yóo pàṣẹ pé kí wọn yọ àwọn òkúta tí àrùn wà lára wọn, kí wọ́n kó wọn sí ibìkan tí kò mọ́ lẹ́yìn ìlú.

41. Yóo pàṣẹ pé kí wọ́n ha gbogbo ògiri ilé náà yípo, kí wọ́n kó gbogbo ohun tí wọ́n fi rẹ́ ilé, tí wọ́n ha kúrò, kí wọ́n dà á sí ibìkan tí kò mọ́ lẹ́yìn ìlú.

42. Wọn yóo wá wá àwọn òkúta mìíràn, wọn yóo fi dípò àwọn tí wọ́n yọ kúrò, yóo sì fi ohun ìrẹ́lé mìíràn tún ilé náà rẹ́.

43. “Bí àrùn yìí bá tún jẹ jáde lára ilé náà, lẹ́yìn tí ó ti yọ àwọn òkúta àkọ́kọ́ jáde, tí ó ti ha ògiri ilé náà, tí ó sì ti tún un rẹ́,

44. alufaa yóo lọ yẹ ilé náà wò. Bí àrùn náà bá tàn káàkiri lára ògiri ilé náà, a jẹ́ pé àrùn ẹ̀tẹ̀ tí í máa ń tàn káàkiri ni; ilé náà kò mọ́.

45. Wọ́n gbọdọ̀ wó o lulẹ̀ ni, kí wọ́n ru gbogbo òkúta rẹ̀ ati igi tí wọ́n fi kọ́ ọ ati ohun ìrẹ́lé tí wọ́n fi rẹ́ ẹ jáde kúrò láàrin ìlú, lọ sí ibi tí kò mọ́.

46. Ẹnikẹ́ni tí ó bá wọ ilé náà lẹ́yìn tí alufaa ti tì í pa, yóo di aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.

47. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sùn ninu ilé náà tabi tí ó bá jẹun ninu rẹ̀ gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀.

48. “Ṣugbọn bí alufaa bá wá yẹ ilé náà wò, tí àrùn náà kò bá tàn káàkiri lára ògiri rẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n ti tún un rẹ́, alufaa yóo pe ilé náà ní mímọ́, nítorí àrùn náà ti san.

49. Nígbà tí alufaa bá fẹ́ sọ ilé náà di mímọ́, yóo mú ẹyẹ kéékèèké meji ati igi kedari ati aṣọ pupa tẹ́ẹ́rẹ́ kan, ati ewé hisopu,

50. yóo pa ọ̀kan ninu àwọn ẹyẹ náà sinu ìkòkò amọ̀ lórí odò tí ń ṣàn,

Ka pipe ipin Lefitiku 14