Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lefitiku 14:33-45 BIBELI MIMỌ (BM)

33. OLUWA sọ fún Mose ati Aaroni pé,

34. “Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ Kenaani tí n óo fun yín, tí yóo jẹ́ ohun ìní yín, bí mo bá fi àrùn ẹ̀tẹ̀ sí ilé kan ninu ilẹ̀ yín.

35. Ẹni tí ó ni ilé náà yóo wá sọ fún alufaa pé, ‘Ó dàbí ẹni pé àrùn kan wà ní ilé mi.’

36. Kí alufaa pàṣẹ pé kí wọn kó gbogbo ohun tí ó wà ninu ilé náà jáde, kí ó tó lọ yẹ àrùn náà wò; kí ó má baà pe gbogbo ohun tí ó wà ninu ilé náà ní aláìmọ́; lẹ́yìn náà, kí alufaa lọ wo ilé náà.

37. Kí ó yẹ àrùn náà wò, bí ó bá jẹ́ pé lára ògiri ilé ni àrùn yìí wà, tí ibi tí ó wà lára ògiri náà dàbí àwọ̀ ewéko tabi tí ó pọ́n, tí ọ̀gangan ibẹ̀ sì jìn ju ara ògiri lọ.

38. Kí alufaa jáde kúrò ninu ilé náà, kí ó lọ síbi ìlẹ̀kùn, kí ó ti ìlẹ̀kùn ilé náà fún ọjọ́ meje.

39. Alufaa yóo pada wá ní ọjọ́ keje láti yẹ ilé náà wò. Bí àrùn bá ti tàn káàkiri lára ògiri ilé náà,

40. yóo pàṣẹ pé kí wọn yọ àwọn òkúta tí àrùn wà lára wọn, kí wọ́n kó wọn sí ibìkan tí kò mọ́ lẹ́yìn ìlú.

41. Yóo pàṣẹ pé kí wọ́n ha gbogbo ògiri ilé náà yípo, kí wọ́n kó gbogbo ohun tí wọ́n fi rẹ́ ilé, tí wọ́n ha kúrò, kí wọ́n dà á sí ibìkan tí kò mọ́ lẹ́yìn ìlú.

42. Wọn yóo wá wá àwọn òkúta mìíràn, wọn yóo fi dípò àwọn tí wọ́n yọ kúrò, yóo sì fi ohun ìrẹ́lé mìíràn tún ilé náà rẹ́.

43. “Bí àrùn yìí bá tún jẹ jáde lára ilé náà, lẹ́yìn tí ó ti yọ àwọn òkúta àkọ́kọ́ jáde, tí ó ti ha ògiri ilé náà, tí ó sì ti tún un rẹ́,

44. alufaa yóo lọ yẹ ilé náà wò. Bí àrùn náà bá tàn káàkiri lára ògiri ilé náà, a jẹ́ pé àrùn ẹ̀tẹ̀ tí í máa ń tàn káàkiri ni; ilé náà kò mọ́.

45. Wọ́n gbọdọ̀ wó o lulẹ̀ ni, kí wọ́n ru gbogbo òkúta rẹ̀ ati igi tí wọ́n fi kọ́ ọ ati ohun ìrẹ́lé tí wọ́n fi rẹ́ ẹ jáde kúrò láàrin ìlú, lọ sí ibi tí kò mọ́.

Ka pipe ipin Lefitiku 14