Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lefitiku 13:48-59 BIBELI MIMỌ (BM)

48. tabi lára aṣọkáṣọ, kì báà jẹ́ olówùú tabi onírun, tabi lára awọ, tabi lára ohunkohun tí a fi awọ ṣe.

49. Bí ibi tí àrùn yìí wà bá bẹ̀rẹ̀ sí í pọ́n tabi, kí ó ní àwọ̀ bíi ti ewéko, kì báà jẹ́ aṣọ olówùú, tabi ti onírun, tabi kí ó jẹ́ awọ tabi ohunkohun tí a fi awọ ṣe, àrùn ẹ̀tẹ̀ ni; dandan ni kí wọ́n fihan alufaa.

50. Kí alufaa yẹ àrùn náà wò, kí ó sì ti aṣọ tí àrùn náà ràn mọ́ mọ́lé fún ọjọ́ meje.

51. Kí ó yẹ àrùn ara aṣọ náà wò ní ọjọ́ keje, bí ó bá ti tàn káàkiri lára aṣọ tabi awọ náà, ohun yòówù tí wọ́n lè máa fi aṣọ náà ṣe, irú ẹ̀tẹ̀ tí ó máa ń ràn káàkiri ni; kò mọ́.

52. Kí alufaa jó aṣọ náà, ibi yòówù tí àrùn náà lè wà lára rẹ̀, kì báà jẹ́ aṣọ onírun tabi olówùú, tabi ohunkohun tí wọ́n fi awọ ṣe; nítorí pé irú àrùn tí ó máa ń ràn káàkiri ara ni; jíjó ni kí wọ́n jó o níná.

53. “Bí alufaa bá yẹ̀ ẹ́ wò, tí àrùn náà kò bá ràn káàkiri lára aṣọ náà tabi ohun èlò awọ náà,

54. alufaa yóo pàṣẹ pé kí wọ́n fọ ohun èlò tí àrùn wà lára rẹ̀ yìí, yóo sì tún tì í mọ́lé fún ọjọ́ meje sí i.

55. Alufaa yóo tún yẹ ohun èlò tí àrùn náà ràn mọ́ wò lẹ́yìn tí wọ́n bá ti fọ̀ ọ́. Bí ọ̀gangan ibi tí àrùn yìí ràn mọ́ kò bá mọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò tàn káàkiri sí i; sibẹ kò mọ́; jíjó ni ó níláti jó o níná, kì báà jẹ́ iwájú, tabi ẹ̀yìn aṣọ tabi awọ náà ni àrùn ràn mọ́.

56. Ṣugbọn nígbà tí alufaa bá yẹ̀ ẹ́ wò, tí ó sì rí i pé àrùn náà ti wòdú lẹ́yìn tí a fọ aṣọ náà, kí ó gé ọ̀gangan ibẹ̀ kúrò lára ẹ̀wù, tabi aṣọ, tabi awọ náà.

57. Bí ó bá tún jẹ jáde lára ẹ̀wù, tabi lára aṣọ, tabi ohun èlò aláwọ náà, a jẹ́ pé ó bẹ̀rẹ̀ sí tàn káàkiri nìyí, jíjó ni kí ó jó ohun èlò náà níná.

58. Ṣugbọn ẹ̀wù tabi aṣọ, tabi ohun èlò awọ, tí àrùn yìí bá lọ kúrò lára rẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n ti fọ̀ ọ́, kí olúwarẹ̀ tún un fọ̀ lẹẹkeji, yóo sì di mímọ́.”

59. Ó jẹ́ òfin tí ó jẹmọ́ àrùn ẹ̀tẹ̀ tí ó bá wà lára ẹ̀wù tabi aṣọ, láti fi mọ̀ bóyá ó mọ́ tabi kò mọ́, kì báà jẹ́ aṣọ onírun tabi olówùú, tabi ohun èlò aláwọ.

Ka pipe ipin Lefitiku 13