Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lefitiku 13:1-3 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA sọ fún Mose ati Aaroni pé,

2. “Nígbà tí ibìkan bá lé lára eniyan, tabi tí ara eniyan bá wú tí ọ̀gangan ibẹ̀ sì ń dán, tí ó bá jọ ẹ̀tẹ̀ ní ara rẹ̀, kí wọ́n mú olúwarẹ̀ tọ Aaroni, alufaa wá; tabi kí wọ́n mú un wá sí ọ̀dọ̀ ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Aaroni, tí ó jẹ́ alufaa.

3. Kí alufaa náà yẹ ọ̀gangan ibi tí àrùn náà wà lára ẹni náà wò. Bí irun ọ̀gangan ibẹ̀ bá di funfun, tí àrùn náà bá jẹ wọ inú ara ẹni náà lọ, tí ó jìn ju awọ ara rẹ̀ lọ, àrùn ẹ̀tẹ̀ ni. Nígbà tí alufaa bá yẹ̀ ẹ́ wò, kí ó pè é ní aláìmọ́.

Ka pipe ipin Lefitiku 13