Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Kinni 9:8-15 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Ibineaya, ọmọ Jerohamu, Ela, ọmọ Usi, ọmọ Mikiri, Meṣulamu, ọmọ Ṣefataya, ọmọ Reueli, ọmọ Ibinija.

9. Àwọn ìbátan wọn gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti tò wọ́n sinu ìwé jẹ́ ẹẹdẹgbẹrun ó lé mẹrindinlọgọta (956). Gbogbo wọn jẹ́ baálé ninu ìdílé wọn, tí ń gbé Jerusalẹmu.

10. Àwọn alufaa tí wọn ń gbé Jerusalẹmu nìwọ̀nyí: Jedaaya, Jehoiaribu, Jakini,

11. ati Asaraya ọmọ Hilikaya, ọmọ Meṣulamu, ọmọ Sadoku, ọmọ Meraiotu, ọmọ Ahitubu, olórí àwọn òṣìṣẹ́ ní ilé Ọlọrun;

12. ati Adaaya, ọmọ Jerohamu, ọmọ Paṣuri, ọmọ Malikija ati Maasai ọmọ Adieli, ọmọ Jasera, ọmọ Meṣulamu, ọmọ Meṣilemiti, ọmọ Imeri.

13. Àwọn tí wọ́n lè ṣiṣẹ́ ní ilé Ọlọrun láìka àwọn eniyan wọn ati àwọn olórí ìdílé wọn gbogbo jẹ́ ẹgbẹsan ó dín ogoji (1,760).

14. Àwọn ọmọ Lefi tí wọn ń gbé Jerusalẹmu nìwọ̀nyí: Ṣemaaya ọmọ Haṣihubu, ọmọ Asirikamu, ọmọ Haṣabaya, lára àwọn ọmọ Merari;

15. ati Bakibakari, Hereṣi, Galali ati Matanaya ọmọ Mika, ọmọ Sikiri, ọmọ Asafu,

Ka pipe ipin Kronika Kinni 9