Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Kinni 5:8-21 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Bela, ọmọ Asasi, ọmọ Ṣema, ọmọ Joẹli, tí wọn ń gbé Aroeri títí dé Nebo ati Baali Meoni.

9. Ilẹ̀ wọn lọ ní apá ìlà oòrùn títí dé àtiwọ aṣálẹ̀, ati títí dé odò Yufurate, nítorí pé ẹran ọ̀sìn wọn pọ̀ ní ilẹ̀ Gileadi.

10. Ní àkókò ọba Saulu, àwọn ẹ̀yà Reubẹni wọnyi gbógun ti àwọn ará Hagiriti, wọ́n pa wọ́n run, wọ́n gba ilẹ̀ wọn tí ó wà ní ìhà ìlà oòrùn Gileadi.

11. Àwọn ẹ̀yà Gadi ń gbé òdìkejì ẹ̀yà Reubẹni ní ilẹ̀ Baṣani, títí dé Saleka:

12. Joẹli ni olórí wọn ní ilẹ̀ Baṣani, Safamu ni igbá keji rẹ̀; àwọn olórí yòókù ni Janai ati Ṣafati.

13. Àwọn arakunrin wọn ní ìdílé wọn ni: Mikaeli, Meṣulamu, ati Ṣeba; Jorai, Jakani, Sia, ati Eberi, gbogbo wọn jẹ́ meje.

14. Àwọn ni ọmọ Abihaili, ọmọ Huri, ọmọ Jaroa, ọmọ Gileadi, ọmọ Mikaeli, ọmọ Jeṣiṣai, ọmọ Jahido, ọmọ Busi.

15. Ahi, ọmọ Abidieli, ọmọ Guni ni olórí ìdílé baba wọn;

16. wọ́n ń gbé Gileadi, Baṣani ati àwọn ìlú tí wọ́n yí Baṣani ká, ati ní gbogbo ilẹ̀ pápá Ṣaroni.

17. A kọ àkọsílẹ̀ wọn ní àkókò Jotamu, ọba Juda, ati ní àkókò Jeroboamu ọba Israẹli.

18. Àwọn ẹ̀yà Reubẹni, àwọn ẹ̀yà Gadi, ati ìdajì ẹ̀yà Manase, ní ẹgbaa mejilelogun ati ẹẹdẹgbẹrin ó lé ọgọta (44,760) akọni ọmọ ogun tí wọ́n ń lo asà, idà, ọfà ati ọrun lójú ogun, tí wọ́n gbáradì fún ogun.

19. Wọ́n gbógun ti àwọn ará Hagiriti, Jeturi, Nafiṣi ati Nodabu.

20. Nígbà tí wọ́n rí ìrànlọ́wọ́ gbà, wọ́n ṣẹgun àwọn ará Hagiriti ati àwọn tí wọ́n wà pẹlu wọn, nítorí wọ́n ké pe Ọlọrun lójú ogun náà, ó sì gbọ́ igbe wọn nítorí pé wọ́n gbẹ́kẹ̀lé e.

21. Àwọn ẹran ọ̀sìn tí wọ́n kó lójú ogun nìwọ̀nyí: ẹgbaa mẹẹdọgbọn (50,000) ràkúnmí, ọ̀kẹ́ mejila lé ẹgbaarun (250,000) aguntan, ati ẹgbaa (2,000) kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́; wọ́n sì kó ọ̀kẹ́ marun-un (100,000) ọkunrin lẹ́rú.

Ka pipe ipin Kronika Kinni 5