Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Kinni 5:12-24 BIBELI MIMỌ (BM)

12. Joẹli ni olórí wọn ní ilẹ̀ Baṣani, Safamu ni igbá keji rẹ̀; àwọn olórí yòókù ni Janai ati Ṣafati.

13. Àwọn arakunrin wọn ní ìdílé wọn ni: Mikaeli, Meṣulamu, ati Ṣeba; Jorai, Jakani, Sia, ati Eberi, gbogbo wọn jẹ́ meje.

14. Àwọn ni ọmọ Abihaili, ọmọ Huri, ọmọ Jaroa, ọmọ Gileadi, ọmọ Mikaeli, ọmọ Jeṣiṣai, ọmọ Jahido, ọmọ Busi.

15. Ahi, ọmọ Abidieli, ọmọ Guni ni olórí ìdílé baba wọn;

16. wọ́n ń gbé Gileadi, Baṣani ati àwọn ìlú tí wọ́n yí Baṣani ká, ati ní gbogbo ilẹ̀ pápá Ṣaroni.

17. A kọ àkọsílẹ̀ wọn ní àkókò Jotamu, ọba Juda, ati ní àkókò Jeroboamu ọba Israẹli.

18. Àwọn ẹ̀yà Reubẹni, àwọn ẹ̀yà Gadi, ati ìdajì ẹ̀yà Manase, ní ẹgbaa mejilelogun ati ẹẹdẹgbẹrin ó lé ọgọta (44,760) akọni ọmọ ogun tí wọ́n ń lo asà, idà, ọfà ati ọrun lójú ogun, tí wọ́n gbáradì fún ogun.

19. Wọ́n gbógun ti àwọn ará Hagiriti, Jeturi, Nafiṣi ati Nodabu.

20. Nígbà tí wọ́n rí ìrànlọ́wọ́ gbà, wọ́n ṣẹgun àwọn ará Hagiriti ati àwọn tí wọ́n wà pẹlu wọn, nítorí wọ́n ké pe Ọlọrun lójú ogun náà, ó sì gbọ́ igbe wọn nítorí pé wọ́n gbẹ́kẹ̀lé e.

21. Àwọn ẹran ọ̀sìn tí wọ́n kó lójú ogun nìwọ̀nyí: ẹgbaa mẹẹdọgbọn (50,000) ràkúnmí, ọ̀kẹ́ mejila lé ẹgbaarun (250,000) aguntan, ati ẹgbaa (2,000) kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́; wọ́n sì kó ọ̀kẹ́ marun-un (100,000) ọkunrin lẹ́rú.

22. Ọpọlọpọ eniyan ni wọ́n pa, nítorí pé Ọlọrun ni ó jà fún wọn; wọ́n sì ń gbé ilẹ̀ àwọn ọ̀tá wọn títí tí àwọn ará Asiria fi kó wọn lẹ́rú.

23. Ìdajì ẹ̀yà Manase ń gbé Baṣani, wọ́n pọ̀ pupọ; wọ́n tàn ká títí dé Baali Herimoni, Seniri, ati òkè Herimoni.

24. Àwọn Olórí ìdílé wọn nìwọ̀nyí: Eferi, Iṣi, Elieli, ati Asirieli; Jeremaya, Hodafaya ati Jahidieli, akikanju jagunjagun ni wọ́n, wọ́n sì jẹ́ olókìkí ati olórí ní ilé baba wọn.

Ka pipe ipin Kronika Kinni 5