Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Kinni 29:7-13 BIBELI MIMỌ (BM)

7. Àwọn nǹkan tí wọ́n fi sílẹ̀ fún iṣẹ́ ilé OLUWA nìwọ̀nyí: ẹgbẹẹdọgbọn (5,000) talẹnti wúrà, ẹgbaarun (10,000) ìwọ̀n talẹnti fadaka, ẹgbaasan-an (18,000) ìwọ̀n talẹnti idẹ ati ọ̀kẹ́ marun-un (100,000) ìwọ̀n talẹnti irin.

8. Gbogbo àwọn tí wọ́n ní òkúta olówó iyebíye ni wọ́n mú wọn wá tí wọ́n fi wọ́n sí ibi ìṣúra ilé OLUWA, tí ó wà lábẹ́ àbojútó Jehieli ará Geriṣoni.

9. Inú àwọn eniyan náà dùn pé wọ́n fi tinútinú mú ọrẹ wá nítorí pé tọkàntọkàn ati tìfẹ́tìfẹ́ ni wọ́n fi mú ọrẹ wá fún OLUWA; inú Dafidi ọba náà sì dùn pupọ pẹlu.

10. Nítorí náà, Dafidi yin OLUWA níwájú gbogbo eniyan, ó ní: “Ìyìn ni fún ọ títí lae, OLUWA, Ọlọrun Israẹli, Baba ńlá wa,

11. OLUWA, o tóbi pupọ, tìrẹ ni agbára, ògo, ìṣẹ́gun, ati ọlá ńlá; nítorí tìrẹ ni ohun gbogbo ní ọ̀run ati ní ayé. Tìrẹ ni ìjọba, a gbé ọ ga bí orí fún ohun gbogbo.

12. Láti ọ̀dọ̀ rẹ wá ni ọrọ̀ ati ọlá ti ń wá, o sì ń jọba lórí ohun gbogbo. Ìkáwọ́ rẹ ni ipá ati agbára wà, ó wà ní ìkáwọ́ rẹ láti gbéni ga ati láti fún ni lágbára.

13. A dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, Ọlọrun wa, a sì yin orúkọ rẹ tí ó lógo.

Ka pipe ipin Kronika Kinni 29