Inú àwọn eniyan náà dùn pé wọ́n fi tinútinú mú ọrẹ wá nítorí pé tọkàntọkàn ati tìfẹ́tìfẹ́ ni wọ́n fi mú ọrẹ wá fún OLUWA; inú Dafidi ọba náà sì dùn pupọ pẹlu.