Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Kinni 29:20-30 BIBELI MIMỌ (BM)

20. Dafidi sọ fún gbogbo ìjọ eniyan pé, “Ẹ yin OLUWA Ọlọrun yín.” Gbogbo wọn bá yin OLUWA Ọlọrun àwọn baba wọn. Wọ́n wólẹ̀, wọ́n sin OLUWA, wọ́n sì tẹríba fún ọba.

21. Ní ọjọ́ keji, wọ́n fi ẹgbẹrun akọ mààlúù rú ẹbọ sísun sí OLUWA, ati ẹgbẹrun àgbò, ati ẹgbẹrun ọ̀dọ́ aguntan, pẹlu ọrẹ ohun mímu ati ọpọlọpọ ẹbọ fún gbogbo àwọn ọmọ Israẹli.

22. Wọ́n jẹ, wọ́n sì mu níwájú Ọlọrun ní ọjọ́ náà pẹlu ayọ̀ ńlá.Wọ́n tún fi Solomoni, ọmọ Dafidi, jẹ ọba lẹẹkeji. Wọ́n fi òróró yàn án ní ọba ní orúkọ OLUWA, Sadoku sì ni alufaa.

23. Solomoni jókòó lórí ìtẹ́ OLUWA gẹ́gẹ́ bí ọba, dípò Dafidi, baba rẹ̀. Solomoni ní ìlọsíwájú, gbogbo àwọn eniyan Israẹli sì ń gbọ́ tirẹ̀.

24. Gbogbo àwọn ìjòyè, àwọn alágbára, ati gbogbo àwọn ọmọ Dafidi ọba ni wọ́n jẹ́jẹ̀ẹ́ láti máa gbọ́ ti Solomoni.

25. OLUWA gbé Solomoni ga lójú gbogbo àwọn ọmọ Israẹli, ó sì fún un ní ọlá ju gbogbo àwọn ọba tí wọ́n ti jẹ ṣáájú rẹ̀ ní Israẹli.

26. Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi, ọmọ Jese, ṣe jọba lórí gbogbo Israẹli.

27. Ó jọba fún ogoji ọdún; ó jọba fún ọdún meje ní Heburoni, ó sì jọba fún ọdún mẹtalelọgbọn ní Jerusalẹmu.

28. Ẹ̀mí rẹ̀ gùn, ó lọ́rọ̀, ó sì lọ́lá, ó sì di arúgbó kàngẹ́kàngẹ́ kí ó tó kú, Solomoni ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀.

29. Ìtàn ìgbé ayé ọba Dafidi láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin ni a kọ sí inú ìwé ìtàn tí wolii Samuẹli kọ, èyí tí wolii Natani kọ, ati èyí tí wolii Gadi kọ.

30. Àkọsílẹ̀ yìí sọ bí ó ti ṣe ìjọba rẹ̀, bí agbára rẹ̀ ti tó; ati gbogbo nǹkan tí ó ṣẹlẹ̀ sí i, ati èyí tí ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọmọ Israẹli ati sí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n wà ní àyíká wọn.

Ka pipe ipin Kronika Kinni 29