Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Kinni 29:12-19 BIBELI MIMỌ (BM)

12. Láti ọ̀dọ̀ rẹ wá ni ọrọ̀ ati ọlá ti ń wá, o sì ń jọba lórí ohun gbogbo. Ìkáwọ́ rẹ ni ipá ati agbára wà, ó wà ní ìkáwọ́ rẹ láti gbéni ga ati láti fún ni lágbára.

13. A dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, Ọlọrun wa, a sì yin orúkọ rẹ tí ó lógo.

14. “Ṣugbọn, kí ni mo jẹ́, kí sì ni àwọn eniyan mi jẹ́, tí a fi lè mú ọrẹ tí ó pọ̀ tó báyìí wá fún Ọlọrun tọkàntọkàn? Nítorí láti ọ̀dọ̀ rẹ ni ohun gbogbo ti wá, ninu ohun tí o fún wa ni a sì ti mú wá fún ọ.

15. Àjèjì ati àlejò ni a jẹ́ ní ojú rẹ, gẹ́gẹ́ bí àwọn baba ńlá wa. Gbogbo ọjọ́ wa láyé dàbí òjìji, kò lè wà pẹ́ títí.

16. OLUWA, Ọlọrun wa, tìrẹ ni gbogbo ohun tí a mú wá, láti fi kọ́ ilé fún orúkọ mímọ́ rẹ, ọ̀dọ̀ rẹ ni wọ́n sì ti wá.

17. Ọlọrun mi, mo mọ̀ pé ò máa yẹ ọkàn wò, o sì ní inú dídùn sí òtítọ́; tọkàntọkàn mi ni mo fi mú gbogbo nǹkan wọnyi wá fún ọ, mo sì ti rí i bí àwọn eniyan rẹ ti fi tọkàntọkàn ati inú dídùn mú ọrẹ wọn wá fún ọ.

18. OLUWA Ọlọrun àwọn baba wa: Abrahamu, Isaaki ati Israẹli, jẹ́ kí irú ẹ̀mí yìí túbọ̀ máa wà ninu àwọn eniyan rẹ títí lae, kí o sì jẹ́ kí ọkàn wọn máa fà sí ọ̀dọ̀ rẹ.

19. Jọ̀wọ́, jẹ́ kí Solomoni ọmọ mi, fi gbogbo ọkàn rẹ̀ pa òfin, àṣẹ ati ìlànà rẹ mọ́, kí ó lè ṣe ohun gbogbo, kí ó sì lè kọ́ tẹmpili tí mo ti múra rẹ̀ sílẹ̀ fún.”

Ka pipe ipin Kronika Kinni 29