Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Kinni 28:12-16 BIBELI MIMỌ (BM)

12. ati àwòrán gbogbo ohun tí ó ní lọ́kàn láti ṣe sinu àgbàlá ilé OLUWA, ati ti àwọn yàrá káàkiri, àwọn ilé ìṣúra tí yóo wà ninu ilé Ọlọrun, ati ti àwọn ilé ìṣúra tí wọ́n o máa kó ohun tí a yà sọ́tọ̀ fún OLUWA pamọ́ sí.

13. Dafidi tún fún un ní ìwé ètò pípín àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi sí ìsọ̀rí-ìsọ̀rí, ati ètò gbogbo iṣẹ́ ìsìn inú ilé OLUWA, ti àwọn ohun èlò fún ìsìn ninu ilé OLUWA;

14. àkọsílẹ̀ ìwọ̀n wúrà fún gbogbo ohun èlò wúrà fún ìsìn kọ̀ọ̀kan, ti ìwọ̀n fadaka fún gbogbo ohun èlò fadaka fún ìsìn kọ̀ọ̀kan,

15. ti ìwọ̀n àwọn ọ̀pá fìtílà wúrà ati àwọn fìtílà wọn, ti ìwọ̀n fadaka fún ọ̀pá fìtílà kan ati àwọn fìtílà wọn, gẹ́gẹ́ bí ìlò olukuluku wọn ninu ìsìn.

16. Ètò ìwọ̀n wúrà fún tabili àkàrà ìfihàn kọ̀ọ̀kan ati ìwọ̀n fadaka fún tabili fadaka kọ̀ọ̀kan,

Ka pipe ipin Kronika Kinni 28