Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Kinni 21:7-18 BIBELI MIMỌ (BM)

7. Inú Ọlọrun kò dùn sí ọ̀rọ̀ náà, nítorí náà ó jẹ àwọn ọmọ Israẹli níyà.

8. Dafidi bá sọ fún Ọlọrun pé, “Mo ti dá ẹ̀ṣẹ̀ ńlá, níti ohun tí mo ṣe yìí. Mo sì bẹ̀bẹ̀ pé kí o dárí ẹ̀ṣẹ̀ yìí ji èmi iranṣẹ rẹ, nítorí pé ìwà òmùgọ̀ ni mo hù.”

9. Ọlọrun bá rán Gadi, aríran Dafidi pé,

10. “Lọ sọ fún Dafidi pé, ‘OLUWA ní, nǹkan mẹta ni òun fi siwaju rẹ, kí o yan èyí tí o bá fẹ́ kí òun ṣe sí ọ ninu wọn.’ ”

11. Gadi bá lọ sọ́dọ̀ Dafidi ó lọ sọ fún un pé, “OLUWA ní kí o yan èyí tí o bá fẹ́ ninu àwọn nǹkan mẹta wọnyi:

12. yálà kí ìyàn mú fún ọdún mẹta, tabi kí àwọn ọ̀tá rẹ máa lé ọ kiri, kí wọ́n sì máa fi idà pa yín fún oṣù mẹta, tabi kí idà OLUWA kọlù ọ́ fún ọjọ́ mẹta, kí àjàkálẹ̀ àrùn sọ̀kalẹ̀ sórí ilẹ̀ náà, kí angẹli Ọlọrun sì máa paniyan jákèjádò ilẹ̀ Israẹli. Sọ èyí tí o bá fẹ́, kí n lè mọ ohun tí n óo sọ fún ẹni tí ó rán mi.”

13. Nígbà náà ni Dafidi wí fún Gadi pé, “Ìdààmú ńlá dé bá mi, jẹ́ kí n ṣubú sí ọwọ́ Ọlọrun, nítorí àánú rẹ̀ pọ̀; má jẹ́ kí n bọ́ sí ọwọ́ eniyan.”

14. Nítorí náà, Ọlọrun rán àjàkálẹ̀ àrùn sórí ilẹ̀ Israẹli, àwọn tí wọ́n kú sì jẹ́ ẹgbaa marundinlogoji (70,000) eniyan.

15. Ọlọrun rán angẹli kan pé kí ó lọ pa Jerusalẹmu run; ṣugbọn bí ó ti fẹ́ pa á run, OLUWA rí i, ó sì yí ọkàn pada, ó wí fún apanirun náà pé, “Ó tó gẹ́ẹ́, dáwọ́ dúró.” Angẹli OLUWA náà bá dúró níbi ìpakà Onani ará Jebusi.

16. Dafidi rí angẹli náà tí ó dúró ní agbede meji ayé ati ọ̀run, tí ó na idà ọwọ́ rẹ̀ sí orí Jerusalẹmu. Dafidi ati àwọn ìjòyè àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wọ aṣọ ọ̀fọ̀ bá dojúbolẹ̀.

17. Dafidi bá sọ fún Ọlọrun pé, “Ṣebí èmi ni mo pàṣẹ pé kí wọ́n lọ ka àwọn eniyan? Èmi ni mo ṣẹ̀, tí mo sì ṣe nǹkan burúkú. Kí ni àwọn aguntan wọnyi ṣe? OLUWA, Ọlọrun mi, mo bẹ̀ ọ́, èmi ati ilé baba mi ni kí o jẹ níyà, má jẹ́ kí àjàkálẹ̀ àrùn yìí wá sórí àwọn eniyan rẹ.”

18. Angẹli OLUWA bá pàṣẹ fún Gadi pé kí ó lọ sọ fún Dafidi pé kí ó lọ tẹ́ pẹpẹ kan fún OLUWA ní ibi ìpakà Onani ará Jebusi.

Ka pipe ipin Kronika Kinni 21