Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Kinni 21:22-27 BIBELI MIMỌ (BM)

22. Dafidi sọ fún un pé, “Ta ibi ìpakà yìí fún mi, kí n lè tẹ́ pẹpẹ kan níbẹ̀ fún OLUWA. Iye tí ó bá tó gan-an ni kí o tà á fún mi, kí àjàkálẹ̀ àrùn yìí lè dáwọ́ dúró.”

23. Onani dá Dafidi lóhùn pé, “olúwa mi, mú gbogbo rẹ̀, kí o sì ṣe ohun tí o bá fẹ́ níbẹ̀. Wò ó, mo tún fún ọ ní àwọn akọ mààlúù yìí fún ẹbọ sísun, ati pákó ìpakà fún dídá iná ẹbọ sísun, ati ọkà fún ẹbọ ohun jíjẹ. Mo bùn ọ́ ní gbogbo rẹ̀.”

24. Ṣugbọn Dafidi ọba dá Onani lóhùn pé, “Rárá o, mo níláti ra gbogbo rẹ̀ ní iye tí ó bá tó gan-an ni. N kò ní fún OLUWA ní nǹkan tí ó jẹ́ tìrẹ, tabi kí n rú ẹbọ tí kò ná mi ní ohunkohun sí OLUWA.”

25. Nítorí náà, Dafidi fún Onani ní ẹgbẹta (600) ìwọ̀n ṣekeli wúrà, fún ilẹ̀ ìpakà náà.

26. Dafidi tẹ́ pẹpẹ níbẹ̀, ó rú ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia, ó bá képe OLUWA. OLUWA dá a lóhùn: ó rán iná sọ̀kalẹ̀ láti jó ẹbọ sísun náà.

27. OLUWA pàṣẹ fún angẹli náà pé kí ó ti idà rẹ̀ bọ inú àkọ̀, ó sì ṣe bẹ́ẹ̀.

Ka pipe ipin Kronika Kinni 21