Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Kinni 21:17-30 BIBELI MIMỌ (BM)

17. Dafidi bá sọ fún Ọlọrun pé, “Ṣebí èmi ni mo pàṣẹ pé kí wọ́n lọ ka àwọn eniyan? Èmi ni mo ṣẹ̀, tí mo sì ṣe nǹkan burúkú. Kí ni àwọn aguntan wọnyi ṣe? OLUWA, Ọlọrun mi, mo bẹ̀ ọ́, èmi ati ilé baba mi ni kí o jẹ níyà, má jẹ́ kí àjàkálẹ̀ àrùn yìí wá sórí àwọn eniyan rẹ.”

18. Angẹli OLUWA bá pàṣẹ fún Gadi pé kí ó lọ sọ fún Dafidi pé kí ó lọ tẹ́ pẹpẹ kan fún OLUWA ní ibi ìpakà Onani ará Jebusi.

19. Dafidi bá dìde gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Gadi, tí ó sọ ní orúkọ OLÚWA.

20. Onani ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin mẹrin wà níbi tí wọ́n ti ń pakà. Nígbà tí wọ́n rí angẹli náà, wọ́n sápamọ́.

21. Bí Dafidi ti dé ọ̀dọ̀ Onani, tí Onani rí i, ó kúrò níbi tí ó ti ń pa ọkà, ó lọ tẹríba fún Dafidi, ó dojúbolẹ̀.

22. Dafidi sọ fún un pé, “Ta ibi ìpakà yìí fún mi, kí n lè tẹ́ pẹpẹ kan níbẹ̀ fún OLUWA. Iye tí ó bá tó gan-an ni kí o tà á fún mi, kí àjàkálẹ̀ àrùn yìí lè dáwọ́ dúró.”

23. Onani dá Dafidi lóhùn pé, “olúwa mi, mú gbogbo rẹ̀, kí o sì ṣe ohun tí o bá fẹ́ níbẹ̀. Wò ó, mo tún fún ọ ní àwọn akọ mààlúù yìí fún ẹbọ sísun, ati pákó ìpakà fún dídá iná ẹbọ sísun, ati ọkà fún ẹbọ ohun jíjẹ. Mo bùn ọ́ ní gbogbo rẹ̀.”

24. Ṣugbọn Dafidi ọba dá Onani lóhùn pé, “Rárá o, mo níláti ra gbogbo rẹ̀ ní iye tí ó bá tó gan-an ni. N kò ní fún OLUWA ní nǹkan tí ó jẹ́ tìrẹ, tabi kí n rú ẹbọ tí kò ná mi ní ohunkohun sí OLUWA.”

25. Nítorí náà, Dafidi fún Onani ní ẹgbẹta (600) ìwọ̀n ṣekeli wúrà, fún ilẹ̀ ìpakà náà.

26. Dafidi tẹ́ pẹpẹ níbẹ̀, ó rú ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia, ó bá képe OLUWA. OLUWA dá a lóhùn: ó rán iná sọ̀kalẹ̀ láti jó ẹbọ sísun náà.

27. OLUWA pàṣẹ fún angẹli náà pé kí ó ti idà rẹ̀ bọ inú àkọ̀, ó sì ṣe bẹ́ẹ̀.

28. Nígbà tí Dafidi rí i pé OLUWA ti gbọ́ adura rẹ̀ ní ibi ìpakà Onani ará Jebusi, ó bẹ̀rẹ̀ sí rú àwọn ẹbọ rẹ̀ níbẹ̀.

29. Títí di àkókò yìí, àgọ́ OLUWA tí Mose pa ní aṣálẹ̀, ati pẹpẹ ẹbọ sísun wà ní ibi pẹpẹ ìrúbọ ní Gibeoni.

30. Ṣugbọn Dafidi kò lè lọ sibẹ láti wádìí lọ́wọ́ Ọlọrun nítorí ó ń bẹ̀rù idà angẹli OLUWA.

Ka pipe ipin Kronika Kinni 21