Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Keji 6:3-21 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Israẹli wà níbẹ̀, ọba bá yíjú pada sí wọn, ó sì gbadura fún wọn.

4. Lẹ́yìn náà, ó ní, “Ẹni ìyìn ni OLUWA Ọlọrun Israẹli, tí ó mú ohun gbogbo tí ó wí fún Dafidi, baba mi, ṣẹ fúnrarẹ̀, nítorí ó wí pé,

5. ‘Láti ìgbà tí mo ti mú àwọn eniyan jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti, n kò tíì yan ìlú kankan ninu ẹ̀yà Israẹli láti kọ́ ilé sí fún ìjọ́sìn ní orúkọ mi, bẹ́ẹ̀ ni n kò yan ẹnìkan kan láti jẹ́ olórí àwọn eniyan mi.

6. Ṣugbọn nisinsinyii, mo yan Jerusalẹmu fún ibi ìjọ́sìn ní orúkọ mi, mo sì ti yan Dafidi láti jẹ́ olórí Israẹli, eniyan mi.’ ”

7. Ó wu Dafidi, baba mi, láti kọ́ ilé kan fún ìjọ́sìn ní orúkọ OLUWA Ọlọrun Israẹli.

8. Ṣugbọn OLUWA sọ fún baba mi pé nǹkan dáradára ni pé ó wù ú lọ́kàn láti kọ́ ilé kan fún òun Ọlọrun,

9. ṣugbọn kì í ṣe òun ni yóo kọ́ ilé náà, ọmọ bíbí inú rẹ̀ ni yóo kọ́ ilé fún òun.

10. “Nisinsinyii OLUWA ti mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Mo ti wà ní ipò baba mi, mo ti gorí ìtẹ́ ọba Israẹli, bí OLUWA ti ṣèlérí, mo sì ti kọ́ tẹmpili fún OLUWA Ọlọrun Israẹli.

11. Mo ti gbé àpótí ẹ̀rí sibẹ, inú rẹ̀ sì ni majẹmu tí OLUWA bá àwọn eniyan Israẹli dá wà.”

12. Lẹ́yìn náà, Solomoni dúró níwájú pẹpẹ lójú gbogbo eniyan, ó gbé ọwọ́ mejeeji sókè, ó sì gbadura sí Ọlọrun.

13. Solomoni ti ṣe pẹpẹ bàbà kan, ó gbé e sí àgbàlá ilé náà. Gígùn ati ìbú rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ marun-un (mita 2¼), gíga rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹta (1.3 mita). Solomoni gun orí pẹpẹ yìí, níbi tí gbogbo eniyan ti lè rí i. Ó kúnlẹ̀, ó gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè sí Ọlọrun;

14. ó bá gbadura pé, “OLUWA, Ọlọrun Israẹli, kò sí Ọlọrun tí ó dàbí rẹ ní ọ̀run tabi ní ayé, ìwọ tí ò ń pa majẹmu mọ́, tí o sì ń fi ìfẹ́ ńlá han àwọn iranṣẹ rẹ, tí wọn ń fi tọkàntọkàn tẹ̀lé ìlànà rẹ.

15. O ti mú ìlérí rẹ ṣẹ fún baba mi, Dafidi, iranṣẹ rẹ. O fi ẹnu rẹ ṣèlérí, o sì ti fi ọwọ́ ara rẹ mú ìlérí náà ṣẹ lónìí.

16. Nisinsinyii, OLUWA Ọlọrun Israẹli, jẹ́ kí ìlérí tí o ṣe fún Dafidi, baba mi ṣẹ, pé, ìran rẹ̀ ni yóo máa jọba ní Israẹli títí lae, bí wọn bá ń tẹ̀lé ìlànà rẹ, tí wọ́n sì ń pa òfin rẹ mọ́ gẹ́gẹ́ bí Dafidi ti ṣe.

17. Nisinsinyii, jọ̀wọ́ Ọlọrun Israẹli, mú ọ̀rọ̀ rẹ tí o sọ fún Dafidi, iranṣẹ rẹ ṣẹ.

18. “Ṣugbọn ṣé ìwọ Ọlọrun yóo máa bá eniyan gbé lórí ilẹ̀ ayé? Bí ọ̀run ti tóbi tó, kò gbà ọ́, mélòó mélòó ni ilé tí mo kọ́ yìí?

19. Sibẹsibẹ, jọ̀wọ́ fetí sí adura ati ẹ̀bẹ̀ èmi iranṣẹ rẹ. OLUWA Ọlọrun mi, gbọ́ igbe èmi iranṣẹ rẹ, ati adura tí mò ń gbà níwájú rẹ.

20. Máa bojútó ilé yìí tọ̀sán-tòru. O ti sọ pé ibẹ̀ ni àwọn eniyan yóo ti máa jọ́sìn ní orúkọ rẹ. Jọ̀wọ́ máa gbọ́ adura tí èmi iranṣẹ rẹ bá gbà nígbà tí mo bá kọjú sí ilé yìí.

21. Gbọ́ ẹ̀bẹ̀ èmi iranṣẹ rẹ, ati ti Israẹli, eniyan rẹ, nígbà tí wọ́n bá kọjú sí ibí yìí láti gbadura. Gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wa láti ibùgbé rẹ ní ọ̀run, kí o sì dáríjì wá.

Ka pipe ipin Kronika Keji 6