Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Keji 6:26-32 BIBELI MIMỌ (BM)

26. “Nígbà tí òjò bá kọ̀ tí kò rọ̀, nítorí pé àwọn eniyan rẹ ṣẹ̀, bí wọ́n bá kọjú sí ilé yìí, tí wọ́n sì gbadura, tí wọ́n jẹ́wọ́ orúkọ rẹ, tí wọ́n yipada kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ wọn, nítorí pé o ti jẹ wọ́n níyà,

27. jọ̀wọ́, gbọ́ láti ọ̀run, kí o sì dáríjì àwọn eniyan Israẹli, àwọn iranṣẹ rẹ. Tọ́ wọn sí ọ̀nà tí wọn yóo máa tọ̀, kí o sì jẹ́ kí òjò rọ̀ sí ilẹ̀ tí o fún àwọn eniyan rẹ gẹ́gẹ́ bí ìní wọn.

28. “Nígbàkúùgbà tí ìyàn bá mú ní ilẹ̀ yìí, tabi tí àjàkálẹ̀ àrùn bá bẹ́ sílẹ̀, tabi ọ̀gbẹlẹ̀, tabi ìrẹ̀dànù ohun ọ̀gbìn, tabi eṣú, tabi kòkòrò tíí máa jẹ ohun ọ̀gbìn; tabi tí àwọn ọ̀tá bá gbógun ti èyíkéyìí ninu àwọn ìlú wọn, irú ìyọnu tabi àìsàn yòówù tí ó lè jẹ́,

29. gbọ́ adura ati ẹ̀bẹ̀ ẹnìkọ̀ọ̀kan, tabi ti gbogbo Israẹli, eniyan rẹ, lẹ́yìn tí olukuluku ti mọ ìṣòro ati ìbànújẹ́ rẹ̀, bí wọ́n bá gbé ọwọ́ adura wọn sókè sí ìhà ilé yìí,

30. jọ̀wọ́, gbọ́ láti ilé rẹ ní ọ̀run, dáríjì wọ́n, kí o sì ṣe ẹ̀tọ́ fún olukuluku gẹ́gẹ́ bí ìwà rẹ̀, nítorí ìwọ nìkan ni o mọ ọkàn ọmọ eniyan.

31. Kí àwọn eniyan rẹ lè máa bẹ̀rù rẹ, kí wọ́n sì máa rìn ní ọ̀nà rẹ ní gbogbo ọjọ́ ayé wọn lórí ilẹ̀ tí o fún àwọn baba wa.

32. “Bákan náà, nígbà tí àwọn àjèjì, tí kì í ṣe ara àwọn ọmọ Israẹli, eniyan rẹ, bá ti ọ̀nà jíjìn wá, láti gbadura sí ìhà ilé yìí, nítorí orúkọ ńlá rẹ, ati iṣẹ́ ńlá, ati agbára rẹ,

Ka pipe ipin Kronika Keji 6