Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Keji 4:6-16 BIBELI MIMỌ (BM)

6. Ó ṣe abọ́ ńlá mẹ́wàá, ó gbé marun-un ka ẹ̀gbẹ́ gúsù, ó sì gbé marun-un yòókù ka ẹ̀gbẹ́ àríwá. Àwọn abọ́ wọnyi ni wọ́n fi ń bu omi láti fọ àwọn ohun tí wọn ń lò fún ẹbọ sísun. Omi inú agbada náà sì ni àwọn alufaa máa ń lò láti fi wẹ̀.

7. Solomoni ṣe ọ̀pá fìtílà wúrà mẹ́wàá bí àpẹẹrẹ tí wọ́n fún un. Ó gbé wọn kalẹ̀ ninu tẹmpili: marun-un ní ìhà gúsù, marun-un yòókù ní ìhà àríwá.

8. Ó ṣe tabili mẹ́wàá, ó gbé wọn kalẹ̀ ninu tẹmpili: marun-un ní ìhà gúsù, marun-un yòókù ní ìhà àríwá. Ó sì ṣe ọgọrun-un àwo kòtò wúrà.

9. Ó kọ́ gbọ̀ngàn kan fún àwọn alufaa, ati òmíràn tí ó tóbi, ó ṣe ìlẹ̀kùn sí wọn, ó sì yọ́ idẹ bo àwọn ìlẹ̀kùn náà.

10. Ó gbé agbada omi kalẹ̀ sí apá gúsù ìhà ìlà oòrùn igun ilé náà.

11. Huramu mọ ìkòkò, ó rọ ọkọ́, ó sì ṣe àwọn àwo kòtò. Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe parí iṣẹ́ tí ó ṣe sinu ilé Ọlọrun fún Solomoni ọba.

12. Àwọn iṣẹ́ náà nìwọ̀nyí: Òpó meji, àwọn ọpọ́n meji tí wọ́n dàbí abọ́ tí wọ́n wà lórí àwọn òpó náà, nǹkankan tí ó dàbí ẹ̀wọ̀n tí wọ́n fi dárà sára àwọn ọpọ́n tí ó wà lórí òpó náà,

13. àwọn irinwo òdòdó idẹ tí wọ́n fi ṣe ọnà ní ìlà meji meji yí ọpọ́n orí àwọn òpó náà ká.

14. Ó ṣe àwọn abọ́ ńlá ati ìjókòó wọn.

15. Ó ṣe agbada omi kan ati ère mààlúù mejila sí abẹ́ rẹ̀.

16. Ó mọ àwọn ìkòkò, ó rọ ọkọ́ ati àmúga tí wọ́n fi ń mú ẹran, ati gbogbo ohun èlò wọn. Idẹ dídán ni Huramu fi ṣe gbogbo wọn fún Solomoni ọba, fún lílò ninu ilé OLUWA.

Ka pipe ipin Kronika Keji 4