Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Keji 35:1-7 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Josaya ṣe Àjọ Ìrékọjá fún OLUWA ní Jerusalẹmu. Ní ọjọ́ kẹrinla, oṣù kinni ni wọ́n pa ọ̀dọ́ aguntan Àjọ Ìrékọjá.

2. Ó yan àwọn alufaa sí ipò wọn, ó sì gbà wọ́n níyànjú kí wọ́n ṣe iṣẹ́ wọn ninu ilé OLUWA.

3. Ó sọ fún àwọn ọmọ Lefi tí wọn ń kọ́ àwọn ọmọ Israẹli, tí wọ́n sì jẹ́ mímọ́ pé, “Ẹ gbé Àpótí mímọ́ náà sinu ilé tí Solomoni ọmọ Dafidi, ọba Israẹli kọ́. Ẹ kò ní máa gbé e lé èjìká kiri mọ́. Ṣugbọn kí ẹ máa ṣiṣẹ́ fún OLUWA Ọlọrun, ati fún gbogbo eniyan Israẹli.

4. Ẹ kó ara yín jọ ní ìdílé ìdílé ati ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ gẹ́gẹ́ bí ìlànà Dafidi, ọba Israẹli ati ti Solomoni ọmọ rẹ̀.

5. Ẹ dúró ní ibi mímọ́, kí ẹ sì pín ara yín sí ìsọ̀rí-ìsọ̀rí gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé àwọn arakunrin yín. Ìdílé kọ̀ọ̀kan gbọdọ̀ ní àwọn ọmọ Lefi tí wọn yóo wà pẹlu wọn.

6. Kí ẹ pa ọ̀dọ́ aguntan Ìrékọjá, kí ẹ ya ara yín sí mímọ́, kí ẹ múra sílẹ̀ fún àwọn arakunrin yín láti ṣe ohun tí OLUWA sọ láti ẹnu Mose.”

7. Josaya ọba fún gbogbo àwọn tí wọ́n wà níbẹ̀ ní ẹran fún ẹbọ Ìrékọjá. Láti inú agbo ẹran tirẹ̀ ni ó ti mú ẹgbaa mẹẹdogun (30,000) aguntan ati ọmọ ewúrẹ́, ati ẹgbẹẹdogun (3,000) mààlúù fún wọn.

Ka pipe ipin Kronika Keji 35