Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Keji 34:4-11 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Wọ́n wó àwọn oriṣa Baali lulẹ̀ níwájú rẹ̀; ó fọ́ àwọn pẹpẹ turari tí wọ́n wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀. Ó wó àwọn òpó oriṣa Aṣera ati gbogbo àwọn ère tí wọ́n fi igi gbẹ́ ati àwọn tí wọ́n fi irin rọ. Ó fọ́ wọn túútúú, ó sì fọ́n wọn ká sórí ibojì àwọn tí wọn ń sìn wọ́n.

5. Ó sun egungun àwọn babalóòṣà lórí pẹpẹ oriṣa wọn. Bẹ́ẹ̀ ló ṣe fọ Jerusalẹmu ati Juda mọ́ tónítóní.

6. Bákan náà ni ó ṣe ní àwọn ìlú Manase, ati ti Efuraimu, ati àwọn ìlú ilẹ̀ Simeoni títí dé ilẹ̀ Nafutali, ati ní gbogbo àyíká wọn.

7. Ó wó àwọn pẹpẹ, ó lọ àwọn òpó Aṣera ati àwọn ère oriṣa lúúlúú, ó sì wó gbogbo pẹpẹ turari jákèjádò ilẹ̀ Israẹli. Lẹ́yìn náà ó pada sí Jerusalẹmu.

8. Ní ọdún kejidinlogun ìjọba Josaya, lẹ́yìn tí ó ti pa ìbọ̀rìṣà rẹ́ ní ilẹ̀ náà, ó rán Ṣafani ọmọ Asalaya láti tún ilé OLUWA Ọlọrun rẹ̀ ṣe pẹlu Maaseaya, gomina ìlú, ati Joa, ọmọ Joahasi tí ó jẹ́ alákòóso ìwé ìrántí.

9. Wọ́n lọ sọ́dọ̀ Hilikaya, olórí alufaa, wọ́n kó owó tí àwọn eniyan mú wá sí ilé OLUWA fún un, tí àwọn Lefi tí wọn ń ṣọ́ ẹnu ọ̀nà gbà lọ́wọ́ àwọn ẹ̀yà Manase, ati Efuraimu ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli yòókù, ati lọ́wọ́ àwọn tí wọn ń gbé Juda, Bẹnjamini ati Jerusalẹmu.

10. Wọ́n kó owó náà fún àwọn tí ń ṣe àbojútó iṣẹ́ náà. Àwọn ni wọ́n ń sanwó fún àwọn tí wọn ń tún ilé OLUWA ṣe.

11. Wọ́n sanwó fún àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà ati àwọn tí wọn ń mọlé, láti ra òkúta gbígbẹ́ ati pákó ati igi, kí wọ́n fi tún àwọn ilé tí àwọn ọba Juda ti sọ di àlàpà kọ́.

Ka pipe ipin Kronika Keji 34