Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Keji 32:22-33 BIBELI MIMỌ (BM)

22. Bẹ́ẹ̀ ni OLUWA ṣe gba Hesekaya ati àwọn ará Jerusalẹmu sílẹ̀ lọ́wọ́ Senakeribu, ọba Asiria, ati gbogbo àwọn ọ̀tá Hesekaya, ó sì fún un ní alaafia.

23. Ọpọlọpọ eniyan mú ẹ̀bùn wá fún OLUWA ní Jerusalẹmu, wọ́n sì mú ẹ̀bùn olówó iyebíye wá fún Hesekaya, ọba Juda. Láti ìgbà náà lọ, àwọn orílẹ̀-èdè káàkiri bẹ̀rẹ̀ sí kókìkí rẹ̀.

24. Ní àkókò kan, Hesekaya ṣàìsàn, ó fẹ́rẹ̀ kú. Ó gbadura, sí OLUWA, OLUWA sì gbọ́ adura rẹ̀, ó sì fún un ní àmì tí ó yani lẹ́nu kan,

25. ṣugbọn Hesekaya ṣe ìgbéraga, kò fi ẹ̀mí ìmoore hàn fún ohun tí Ọlọrun ṣe fún un. Nítorí náà, inú bí OLUWA sí àtòun ati Juda ati Jerusalẹmu.

26. Hesekaya ati àwọn ará Jerusalẹmu bá rẹ ara wọn sílẹ̀, wọ́n sì ronupiwada. Nítorí náà, OLUWA kò bínú sí wọn mọ́ ní ìgbà ayé Hesekaya.

27. Hesekaya ní ọpọlọpọ ọrọ̀ ati ọlá. Ó kọ́ ilé ìṣúra tí ó kó fadaka, ati wúrà, ati òkúta olówó iyebíye, ati turari sí, ati apata ati gbogbo nǹkan olówó iyebíye.

28. Ó kọ́ àká fún ọkà, ọtí waini, ati òróró; ó ṣe ibùjẹ fún oríṣìíríṣìí mààlúù, ó sì ṣe ọgbà fún àwọn aguntan ati ewúrẹ́.

29. Bákan náà, ó kọ́ ọpọlọpọ ìlú fún ara rẹ̀, ó sì ní agbo ẹran lọpọlọpọ, nítorí Ọlọrun ti fún un ní ọrọ̀ lọpọlọpọ.

30. Hesekaya náà ló dí ẹnu odò Gihoni ní apá òkè, ó ya omi rẹ̀ wọ ìhà ìwọ̀ oòrùn ìlú Dafidi. Hesekaya sì ń ní ìlọsíwájú ninu gbogbo iṣẹ́ rẹ̀.

31. Nígbà tí àwọn olórí ilẹ̀ Babiloni ranṣẹ sí i láti mọ̀ nípa ohun ìyanu tí ó ṣẹlẹ̀ ní ilẹ̀ náà, Ọlọrun fi sílẹ̀ láti dán an wò, kí Ọlọrun lè mọ gbogbo ohun tí ó wà lọ́kàn rẹ̀.

32. Àkọsílẹ̀ gbogbo nǹkan yòókù tí Hesekaya ṣe, ati iṣẹ́ rere rẹ̀, wà ninu ìwé ìran wolii Aisaya, ọmọ Amosi ati ninu ìwé ìtàn àwọn ọba Juda ati Israẹli.

33. Nígbà tí Hesekaya kú, wọ́n sin ín sí ara òkè, ninu ibojì àwọn ọmọ Dafidi. Gbogbo àwọn eniyan Juda ati ti Jerusalẹmu ṣe ẹ̀yẹ fún un. Manase, ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀.

Ka pipe ipin Kronika Keji 32