Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Keji 32:19-31 BIBELI MIMỌ (BM)

19. Wọ́n sọ̀rọ̀ Ọlọrun Jerusalẹmu gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn oriṣa àtọwọ́dá tí àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn ń bọ.

20. Hesekaya ati wolii Aisaya, ọmọ Amosi bá fi ìtara gbadura sí Ọlọrun nípa ọ̀rọ̀ yìí.

21. OLUWA bá rán angẹli kan lọ pa gbogbo akọni ọmọ ogun, ati àwọn ọ̀gágun ati àwọn olórí ogun Asiria ní ibùdó wọn. Nítorí náà, pẹlu ìtìjú ńlá ni Senakeribu fi pada lọ sí ìlú rẹ̀. Nígbà tí ó wọ inú ilé oriṣa lọ, àwọn kan ninu àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin bá fi idà pa á.

22. Bẹ́ẹ̀ ni OLUWA ṣe gba Hesekaya ati àwọn ará Jerusalẹmu sílẹ̀ lọ́wọ́ Senakeribu, ọba Asiria, ati gbogbo àwọn ọ̀tá Hesekaya, ó sì fún un ní alaafia.

23. Ọpọlọpọ eniyan mú ẹ̀bùn wá fún OLUWA ní Jerusalẹmu, wọ́n sì mú ẹ̀bùn olówó iyebíye wá fún Hesekaya, ọba Juda. Láti ìgbà náà lọ, àwọn orílẹ̀-èdè káàkiri bẹ̀rẹ̀ sí kókìkí rẹ̀.

24. Ní àkókò kan, Hesekaya ṣàìsàn, ó fẹ́rẹ̀ kú. Ó gbadura, sí OLUWA, OLUWA sì gbọ́ adura rẹ̀, ó sì fún un ní àmì tí ó yani lẹ́nu kan,

25. ṣugbọn Hesekaya ṣe ìgbéraga, kò fi ẹ̀mí ìmoore hàn fún ohun tí Ọlọrun ṣe fún un. Nítorí náà, inú bí OLUWA sí àtòun ati Juda ati Jerusalẹmu.

26. Hesekaya ati àwọn ará Jerusalẹmu bá rẹ ara wọn sílẹ̀, wọ́n sì ronupiwada. Nítorí náà, OLUWA kò bínú sí wọn mọ́ ní ìgbà ayé Hesekaya.

27. Hesekaya ní ọpọlọpọ ọrọ̀ ati ọlá. Ó kọ́ ilé ìṣúra tí ó kó fadaka, ati wúrà, ati òkúta olówó iyebíye, ati turari sí, ati apata ati gbogbo nǹkan olówó iyebíye.

28. Ó kọ́ àká fún ọkà, ọtí waini, ati òróró; ó ṣe ibùjẹ fún oríṣìíríṣìí mààlúù, ó sì ṣe ọgbà fún àwọn aguntan ati ewúrẹ́.

29. Bákan náà, ó kọ́ ọpọlọpọ ìlú fún ara rẹ̀, ó sì ní agbo ẹran lọpọlọpọ, nítorí Ọlọrun ti fún un ní ọrọ̀ lọpọlọpọ.

30. Hesekaya náà ló dí ẹnu odò Gihoni ní apá òkè, ó ya omi rẹ̀ wọ ìhà ìwọ̀ oòrùn ìlú Dafidi. Hesekaya sì ń ní ìlọsíwájú ninu gbogbo iṣẹ́ rẹ̀.

31. Nígbà tí àwọn olórí ilẹ̀ Babiloni ranṣẹ sí i láti mọ̀ nípa ohun ìyanu tí ó ṣẹlẹ̀ ní ilẹ̀ náà, Ọlọrun fi sílẹ̀ láti dán an wò, kí Ọlọrun lè mọ gbogbo ohun tí ó wà lọ́kàn rẹ̀.

Ka pipe ipin Kronika Keji 32