Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Keji 32:11-26 BIBELI MIMỌ (BM)

11. Ó ní bí Hesekaya bá ní OLUWA Ọlọrun wọn yóo gbà wọ́n lọ́wọ́ òun ọba Asiria, ó ń ṣì wọ́n lọ́nà ni, ó fẹ́ kí òùngbẹ ati ebi pa wọ́n kú ni.

12. Ó ní, Ṣebí Hesekaya yìí kan náà ni ó kó gbogbo oriṣa kúrò ní Jerusalẹmu ati ní Juda tí ó sọ fún wọn pé ibi pẹpẹ kan ṣoṣo ni wọ́n ti gbọdọ̀ máa jọ́sìn, kí wọn sì máa rúbọ níbẹ̀?

13. Ó ní ǹjẹ́ wọ́n mọ ohun tí òun ati baba òun ti ṣe sí àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn? Ati pé, ǹjẹ́ àwọn oriṣa àwọn orílẹ̀-èdè náà gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ ọba Asiria?

14. Ó ní èwo ni oriṣa wọn gbà sílẹ̀ lọ́wọ́ òun, ninu gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi tí baba òun parun, tí Ọlọrun tiyín yóo fi wá gbà yín?

15. Ó ní nítorí náà, kí wọn má ṣe jẹ́ kí Hesekaya tàn wọ́n jẹ, tabi kí ó ṣì wọ́n lọ́nà báyìí. Ó ní kí wọn má gbọ́ ohun tí ó ń sọ rárá, nítorí pé kò sí oriṣa orílẹ̀-èdè kan tí ó tó gba àwọn eniyan rẹ̀ lọ́wọ́ òun tabi lọ́wọ́ àwọn baba òun, kí á má wá sọ pé Ọlọrun tiwọn yóo gbà wọ́n lọ́wọ́ òun.”

16. Àwọn iranṣẹ ọba Asiria tún sọ ọ̀rọ̀ burúkú sí OLUWA Ọlọrun ati sí Hesekaya, iranṣẹ rẹ̀.

17. Ọba Asiria yìí kọ àwọn ìwé àfojúdi kan sí OLUWA Ọlọrun Israẹli, ó ní, “Gẹ́gẹ́ bí àwọn oriṣa àwọn orílẹ̀-èdè yòókù kò ti lè gba àwọn eniyan wọn kúrò lọ́wọ́ mi, bẹ́ẹ̀ ni Ọlọrun Hesekaya náà kò ní lè gba àwọn eniyan rẹ̀ lọ́wọ́ mi.”

18. Àwọn iranṣẹ ọba Asiria kígbe sókè nígbà tí wọ́n sọ ọ̀rọ̀ ní èdè Heberu, sí àwọn ará Jerusalẹmu tí wọ́n wà lórí odi, wọn fi dẹ́rùbà wọ́n kí wọ́n lè gba ìlú náà.

19. Wọ́n sọ̀rọ̀ Ọlọrun Jerusalẹmu gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn oriṣa àtọwọ́dá tí àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn ń bọ.

20. Hesekaya ati wolii Aisaya, ọmọ Amosi bá fi ìtara gbadura sí Ọlọrun nípa ọ̀rọ̀ yìí.

21. OLUWA bá rán angẹli kan lọ pa gbogbo akọni ọmọ ogun, ati àwọn ọ̀gágun ati àwọn olórí ogun Asiria ní ibùdó wọn. Nítorí náà, pẹlu ìtìjú ńlá ni Senakeribu fi pada lọ sí ìlú rẹ̀. Nígbà tí ó wọ inú ilé oriṣa lọ, àwọn kan ninu àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin bá fi idà pa á.

22. Bẹ́ẹ̀ ni OLUWA ṣe gba Hesekaya ati àwọn ará Jerusalẹmu sílẹ̀ lọ́wọ́ Senakeribu, ọba Asiria, ati gbogbo àwọn ọ̀tá Hesekaya, ó sì fún un ní alaafia.

23. Ọpọlọpọ eniyan mú ẹ̀bùn wá fún OLUWA ní Jerusalẹmu, wọ́n sì mú ẹ̀bùn olówó iyebíye wá fún Hesekaya, ọba Juda. Láti ìgbà náà lọ, àwọn orílẹ̀-èdè káàkiri bẹ̀rẹ̀ sí kókìkí rẹ̀.

24. Ní àkókò kan, Hesekaya ṣàìsàn, ó fẹ́rẹ̀ kú. Ó gbadura, sí OLUWA, OLUWA sì gbọ́ adura rẹ̀, ó sì fún un ní àmì tí ó yani lẹ́nu kan,

25. ṣugbọn Hesekaya ṣe ìgbéraga, kò fi ẹ̀mí ìmoore hàn fún ohun tí Ọlọrun ṣe fún un. Nítorí náà, inú bí OLUWA sí àtòun ati Juda ati Jerusalẹmu.

26. Hesekaya ati àwọn ará Jerusalẹmu bá rẹ ara wọn sílẹ̀, wọ́n sì ronupiwada. Nítorí náà, OLUWA kò bínú sí wọn mọ́ ní ìgbà ayé Hesekaya.

Ka pipe ipin Kronika Keji 32