Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Keji 29:17-27 BIBELI MIMỌ (BM)

17. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ya ara wọn sí mímọ́ ní ọjọ́ kinni oṣù kinni. Nígbà tí ó di ọjọ́ kẹjọ, wọ́n wá sí yàrá àbáwọlé ilé OLUWA. Ọjọ́ mẹjọ ni wọ́n fi ya ilé OLUWA sí mímọ́, wọ́n parí ní ọjọ́ kẹrindinlogun oṣù náà.

18. Lẹ́yìn náà, wọ́n tọ Hesekaya ọba lọ, wọ́n sọ fún un pé, “A ti tọ́jú ilé OLUWA: ati pẹpẹ ẹbọ sísun, ati gbogbo ohun èlò rẹ̀, ati tabili àkàrà ìfihàn ati gbogbo ohun èlò rẹ̀.

19. Gbogbo àwọn ohun èlò tí Ahasi ọba ti patì nígbà tí ó ṣe aiṣododo ni a ti tọ́jú, tí a sì ti yà sí mímọ́. A ti kó gbogbo wọn siwaju pẹpẹ OLUWA.”

20. Hesekaya ọba dìde ní òwúrọ̀ kutukutu, ó kó gbogbo àwọn ìjòyè ìlú jọ, wọ́n bá lọ sinu ilé OLUWA.

21. Wọ́n fi akọ mààlúù meje, àgbò meje, ọ̀dọ́ aguntan meje ati òbúkọ meje rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ fún ìjọba Hesekaya, ati ilé OLUWA ati ilé Juda. Ọba pàṣẹ pé kí àwọn alufaa, àwọn ọmọ Aaroni, fi wọ́n rúbọ lórí pẹpẹ OLUWA.

22. Àwọn akọ mààlúù ni wọ́n kọ́kọ́ pa, àwọn alufaa gba ẹ̀jẹ̀ wọn, wọ́n dà á sára pẹpẹ. Lẹ́yìn náà wọ́n pa àwọn àgbò, wọ́n sì da ẹ̀jẹ̀ wọn sára pẹpẹ.

23. Lẹ́yìn náà wọ́n kó àwọn òbúkọ fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ wá sọ́dọ̀ ọba ati ìjọ eniyan, wọ́n sì gbé ọwọ́ lé wọn lórí.

24. Àwọn alufaa pa àwọn òbúkọ náà, wọ́n sì fi ẹ̀jẹ̀ wọn rúbọ lórí pẹpẹ fún ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ gbogbo ọmọ Israẹli, nítorí ọba ti pàṣẹ pé wọ́n gbọdọ̀ rú ẹbọ sísun ati ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ fún gbogbo eniyan.

25. Ọba pàṣẹ pé kí àwọn ọmọ Lefi dúró ninu ilé OLUWA pẹlu ohun èlò orin bíi kimbali, hapu ati dùùrù, gẹ́gẹ́ bí i àṣẹ tí OLUWA pa, láti ẹnu Dafidi ati wolii Gadi tí í ṣe aríran ọba, ati wolii Natani.

26. Àwọn ọmọ Lefi dúró pẹlu ohun èlò orin Dafidi, àwọn alufaa sì dúró pẹlu fèrè.

27. Hesekaya pàṣẹ pé kí wọ́n rú ẹbọ sísun lórí pẹpẹ. Nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí rú ẹbọ náà, àwọn akọrin bẹ̀rẹ̀ sí kọrin sí OLUWA pẹlu fèrè ati àwọn ohun èlò orin Dafidi, ọba Israẹli.

Ka pipe ipin Kronika Keji 29