Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Keji 25:1-9 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ẹni ọdún mẹẹdọgbọn ni Amasaya nígbà tí ó jọba; ó sì wà lórí oyè fún ọdún mọkandinlọgbọn ní Jerusalẹmu. Ìyá rẹ̀ ni Jehoadini ará Jerusalẹmu.

2. Ó ṣe ohun tí ó dára lójú OLUWA, ṣugbọn kò fi tọkàntọkàn sìn ín.

3. Lẹ́yìn ìgbà tí ìjọba rẹ̀ ti fẹsẹ̀ múlẹ̀, ó pa gbogbo àwọn tí wọ́n pa baba rẹ̀.

4. Ṣugbọn kò pa àwọn ọmọ wọn, gẹ́gẹ́ bí ìwé òfin Mose ti wí, níbi tí OLUWA ti pàṣẹ, pé, “A kò gbọdọ̀ pa baba nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ọmọ, tabi kí á pa ọmọ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ baba; olukuluku ni yóo kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ara rẹ̀.”

5. Amasaya pe àwọn eniyan Juda ati Bẹnjamini jọ, ó pín wọn sábẹ́ àwọn ọ̀gágun ní ẹgbẹẹgbẹrun ati ọgọọgọrun-un gẹ́gẹ́ bí ilé baba wọn. Àwọn tí wọ́n tó ẹni ogún ọdún ati jù bẹ́ẹ̀ lọ ni gbogbo àwọn tí ó kó jọ. Gbogbo wọn jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹẹdogun (300,000) akọni ọkunrin tí wọ́n tó lọ sójú ogun, tí wọ́n sì lè lo ọ̀kọ̀ ati apata.

6. Ó tún fi ọgọrun-un ìwọ̀n talẹnti fadaka lọ bẹ ọ̀kẹ́ marun-un (100,000) akọni lọ́wẹ̀ ninu àwọn ọmọ ogun Israẹli.

7. Ṣugbọn wolii Ọlọrun kan lọ bá Amasaya, ó sọ fún un pé, “Kabiyesi, má jẹ́ kí àwọn ọmọ ogun Israẹli bá ọ lọ, nítorí OLUWA kò ní wà pẹlu Israẹli ati àwọn ará Efuraimu wọnyi.

8. Ṣugbọn bí o bá wá rò pé àwọn wọnyi ni yóo jẹ́ kí ogun rẹ lágbára, OLUWA yóo bì ọ́ ṣubú níwájú àwọn ọ̀tá rẹ. Nítorí Ọlọrun lágbára láti ranni lọ́wọ́ ati láti bini ṣubú.”

9. Amasaya bèèrè lọ́wọ́ wolii náà pé, “Kí ni kí á ṣe nípa ọgọrun-un talẹnti tí mo ti fún àwọn ọmọ ogun Israẹli?”Ó dáhùn pé, “OLUWA lè fún ọ ní ohun tí ó jù bẹ́ẹ̀ lọ.”

Ka pipe ipin Kronika Keji 25