Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Keji 21:2-13 BIBELI MIMỌ (BM)

2. Jehoramu ní arakunrin mẹfa, tí wọ́n jọ jẹ́ ọmọ Jehoṣafati, orúkọ wọn ni, Asaraya, Jehieli, ati Sakaraya, Asaraya, Mikaeli ati Ṣefataya.

3. Baba wọn fún wọn ní ọpọlọpọ ẹ̀bùn: fadaka, wúrà ati àwọn nǹkan olówó iyebíye, pẹlu àwọn ìlú olódi ní Juda. Ṣugbọn Jehoramu ni ó fi ìjọba lé lọ́wọ́, nítorí pé òun ni àkọ́bí rẹ̀.

4. Nígbà tí ó jọba tán, tí ó sì ti fìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀, ó fi idà pa gbogbo àwọn arakunrin rẹ̀ ati díẹ̀ ninu àwọn olóyè ní Israẹli.

5. Jehoramu jẹ́ ẹni ọdún mejilelọgbọn nígbà tí ó jọba, ó sì wà lórí oyè fún ọdún mẹjọ ní Jerusalẹmu.

6. Ó tẹ̀ sí ọ̀nà burúkú tí àwọn ọba Israẹli rìn, ó ṣe bí ìdílé Ahabu ti ṣe, nítorí pé ọmọ Ahabu ni iyawo rẹ̀. Ó ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA.

7. Sibẹsibẹ OLUWA kò pa ìdílé Dafidi run nítorí majẹmu tí ó ti bá Dafidi dá, ati ìlérí tí ó ti ṣe pé ọmọ rẹ̀ ni yóo máa wà lórí oyè títí lae.

8. Ní àkókò ìjọba Jehoramu ni Edomu ṣọ̀tẹ̀ sí Juda, wọ́n sì yan ọba fún ara wọn.

9. Nítorí náà Jehoramu ati àwọn ọ̀gágun rẹ̀ ati àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ lọ gbógun tì wọ́n. Ní òru, Jehoramu ati ogun rẹ̀ dìde, wọ́n fọ́ ogun Edomu tí ó yí wọn ká tàwọn ti kẹ̀kẹ́ ogun wọn, ati àwọn tí ń wà wọ́n.

10. Láti ìgbà náà ni Edomu ti ń bá Juda ṣọ̀tẹ̀ títí di òní olónìí. Ní àkókò kan náà ni Libina ṣọ̀tẹ̀ sí Juda, ó sì gba òmìnira nítorí pé Jehoramu ti fi ọ̀nà OLUWA àwọn baba rẹ̀ sílẹ̀.

11. Ó tilẹ̀ kọ́ àwọn pẹpẹ ìrúbọ káàkiri ní agbègbè olókè Juda. Ó fa àwọn ará Jerusalẹmu sinu aiṣododo, ó sì kó àwọn ọmọ Juda ṣìnà.

12. Elija wolii kọ ìwé kan sí Jehoramu, ohun tí ó kọ sinu ìwé náà nìyí: “Gbọ́ bí OLUWA Ọlọrun Dafidi, baba rẹ, ti wí; ó ní, nítorí pé o kò tọ ọ̀nà tí Jehoṣafati baba rẹ tọ̀, tabi ti Asa, baba baba rẹ.

13. Ṣugbọn ò ń hùwà bí àwọn ọba Israẹli, o sì ti fa àwọn Juda ati Jerusalẹmu sinu aiṣododo, bí ìdílé Ahabu ti ṣe fún Israẹli. Pataki jùlọ, o pa àwọn arakunrin rẹ, àwọn ọmọ baba rẹ, tí wọ́n tilẹ̀ sàn jù ọ́ lọ.

Ka pipe ipin Kronika Keji 21