Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Keji 20:26-37 BIBELI MIMỌ (BM)

26. Ní ọjọ́ kẹrin, wọ́n péjọ ní àfonífojì Beraka. Ibẹ̀ ni wọ́n ti yin OLUWA. Nítorí náà ni wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ sí pe ibẹ̀ ní Beraka títí di òní olónìí.

27. Jehoṣafati kó gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ pada sí Jerusalẹmu pẹlu ayọ̀ ìṣẹ́gun, nítorí pé OLUWA ti fún un ní ìṣẹ́gun lórí àwọn ọ̀tá rẹ̀.

28. Nígbà tí wọ́n dé Jerusalẹmu, wọ́n wọ inú tẹmpili lọ, pẹlu ìró hapu, ati ti dùùrù ati ti fèrè.

29. Ẹ̀rù OLUWA ba ìjọba gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè nígbà tí wọ́n gbọ́ pé OLUWA bá àwọn ọ̀tá àwọn ọmọ Israẹli jagun.

30. Nítorí náà Jehoṣafati jọba ní alaafia, nítorí pé Ọlọrun fún un ní ìsinmi ní gbogbo àyíká rẹ̀.

31. Jehoṣafati jọba lórí Juda, ẹni ọdún marundinlogoji ni nígbà tí ó gorí oyè. Gbogbo ọdún tí ó lò lórí oyè jẹ́ ọdún mẹẹdọgbọn. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Asuba, ọmọ Ṣilihi.

32. Ó ṣe dáradára gẹ́gẹ́ bí Asa, baba rẹ̀, ó sì ṣe ohun tí ó tọ́ lójú OLUWA.

33. Ṣugbọn kò pa àwọn pẹpẹ ìrúbọ run; àwọn eniyan kò tíì máa fi tọkàntọkàn sin Ọlọrun àwọn baba ńlá wọn.

34. Gbogbo nǹkan yòókù tí Jehoṣafati ṣe láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin, ni a kọ sinu ìwé ìtàn Jehu ọmọ Hanani, tí ó jẹ́ apá kan ìtàn àwọn ọba Israẹli.

35. Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, Jehoṣafati, ọba Juda lọ darapọ̀ mọ́ Ahasaya, ọba Israẹli, tí ó jẹ́ eniyan burúkú.

36. Wọ́n jọ kan àwọn ọkọ̀ ojú omi tí yóo lọ sí ìlú Taṣiṣi. Wọ́n kan àwọn ọkọ̀ náà ní Esiongeberi.

37. Elieseri ọmọ Dodafahu, ará Mareṣa fi àsọtẹ́lẹ̀ bá Jehoṣafati wí. Ó ní, “Nítorí pé o darapọ̀ mọ́ Ahasaya, OLUWA yóo ba ohun tí o ti ṣe tẹ́lẹ̀ jẹ́.” Gbogbo àwọn ọkọ̀ ojú omi náà rì, wọn kò sì lè lọ sí Taṣiṣi mọ́.

Ka pipe ipin Kronika Keji 20