Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Keji 11:2-10 BIBELI MIMỌ (BM)

2. Ṣugbọn OLUWA sọ fún wolii Ṣemaaya, eniyan Ọlọrun pé,

3. “Sọ fún Rehoboamu ọmọ Solomoni, ọba Juda, ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli tí wọn ń gbé Juda ati Bẹnjamini pé,

4. OLUWA ní, ‘Ẹ kò gbọdọ̀ lọ bá àwọn arakunrin yín jà. Kí olukuluku yín pada sí ilé rẹ̀ nítorí èmi ni mo jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yìí ó ṣẹlẹ̀.’ ” Wọ́n gbọ́ràn sí OLUWA lẹ́nu, wọ́n pada, wọn kò sì lọ bá Jeroboamu jagun mọ́.

5. Rehoboamu ń gbé Jerusalẹmu, ó kọ́ àwọn ìlú ààbò wọnyi sí Juda:

6. Bẹtilẹhẹmu, Etamu, ati Tekoa;

7. Betisuri, Soko, ati Adulamu;

8. Gati, Mareṣa, ati Sifi;

9. Adoraimu, Lakiṣi, ati Aseka;

10. Sora, Aijaloni ati Heburoni. Àwọn ni ìlú olódi ní Juda ati Bẹnjamini.

Ka pipe ipin Kronika Keji 11