Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Keji 10:15-19 BIBELI MIMỌ (BM)

15. Ọba kò gbọ́ ti àwọn eniyan náà, nítorí pé ọwọ́ Ọlọrun ni àyípadà yìí ti wá, kí ó lè mú ohun tí ó ní kí wolii Ahija, ará Ṣilo, sọ fún Jeroboamu, ọmọ Nebati, ṣẹ.

16. Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli rí i pé Rehoboamu kò gbọ́ tiwọn, wọ́n dáhùn pé,“Kí ló kàn wá pẹlu ilé Dafidi?Kí ló pa wá pọ̀ pẹlu ọmọ Jese?Ẹ pada sinu àgọ́ yín, ẹ̀yin ọmọ IsraẹliDafidi, fọwọ́ mú ilé rẹ.”Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli bá pada lọ sí ilé wọn,

17. ṣugbọn Rehoboamu jọba lórí àwọn ọmọ Israẹli tí wọn ń gbé Juda.

18. Ọba rán Hadoramu tí ó jẹ́ olórí àwọn akóniṣiṣẹ́ sí àwọn ọmọ Israẹli, ṣugbọn wọ́n sọ ọ́ lókùúta pa. Rehoboamu ọba bá yára bọ́ sinu kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, ó sá àsálà lọ sí Jerusalẹmu.

19. Láti ìgbà náà lọ ni àwọn ọmọ Israẹli ti ń bá ilé Dafidi ṣọ̀tẹ̀ títí di òní olónìí.

Ka pipe ipin Kronika Keji 10