Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joṣua 4:13-19 BIBELI MIMỌ (BM)

13. Nǹkan bíi ọ̀kẹ́ meji (40,000) ọkunrin tí wọ́n ti múra ogun, ni wọ́n rékọjá níwájú OLUWA lọ sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jẹriko.

14. OLUWA gbé Joṣua ga ní ojú gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ní ọjọ́ náà, wọ́n sì bẹ̀rù rẹ̀, bí wọ́n ti bẹ̀rù Mose ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.

15. OLUWA wí fún Joṣua pé,

16. “Pàṣẹ fún àwọn alufaa tí wọ́n gbé Àpótí Ẹ̀rí pé kí wọ́n jáde kúrò ninu odò Jọdani.”

17. Joṣua bá pàṣẹ fún àwọn alufaa náà pé kí wọ́n jáde ninu odò.

18. Nígbà tí àwọn alufaa tí wọ́n gbé Àpótí Majẹmu OLUWA jáde kúrò ninu odò Jọdani, bí wọ́n ti ń gbé ẹsẹ̀ lé ilẹ̀ gbígbẹ, ni omi odò náà pada sí ààyè rẹ̀. Odò náà sì kún bo gbogbo bèbè rẹ̀, bí ó ti wà tẹ́lẹ̀.

19. Ní ọjọ́ kẹwaa oṣù kinni ni àwọn eniyan náà gun òkè odò Jọdani. Wọ́n pàgọ́ sí Giligali ní ìhà ìlà oòrùn Jẹriko.

Ka pipe ipin Joṣua 4