Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joṣua 24:19-33 BIBELI MIMỌ (BM)

19. Ṣugbọn Joṣua dá àwọn eniyan náà lóhùn pé, “Ẹ kò lè sin OLUWA, nítorí pé Ọlọrun mímọ́ ni, Ọlọrun owú sì ni pẹlu, kò sì ní dárí àwọn àìṣedéédé ati ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín.

20. Lẹ́yìn tí OLUWA bá ti ṣe yín lóore, bí ẹ bá kọ̀ ọ́ sílẹ̀, tí ẹ sì bẹ̀rẹ̀ sí bọ àwọn oriṣa àjèjì, yóo yipada láti ṣe yín níbi, yóo sì pa yín run.”

21. Àwọn eniyan náà dá Joṣua lóhùn pé, “Rárá o, OLUWA ni a óo máa sìn.”

22. Joṣua bá wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí ara yín, pé OLUWA ni ẹ yàn láti máa sìn.”Wọ́n dáhùn pé, “Àwa ni ẹlẹ́rìí.”

23. Lẹ́yìn náà, Joṣua sọ fún wọn pé, “Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ kó àwọn oriṣa àjèjì tí ó wà láàrin yín dànù, kí ẹ sì fi ọkàn sọ́dọ̀ OLUWA Ọlọrun Israẹli.”

24. Àwọn eniyan náà dá Joṣua lóhùn pé, “OLUWA Ọlọrun wa ni a óo máa sìn, tirẹ̀ ni a óo sì máa gbọ́.”

25. Joṣua bá dá majẹmu pẹlu àwọn eniyan náà ní ọjọ́ náà, ó sì ṣe òfin ati ìlànà fún wọn ní Ṣekemu.

26. Ó kọ ọ̀rọ̀ náà sinu ìwé òfin Ọlọrun, ó gbé òkúta ńlá kan, ó sì fi gúnlẹ̀ lábẹ́ igi Oaku, ní ibi mímọ́ OLUWA,

27. ó bá wí fún gbogbo wọn pé, “Ẹ wo òkúta yìí, òun ni yóo jẹ́ ẹlẹ́rìí láàrin wa, nítorí pé ó gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ tí OLUWA ti sọ fún wa, nítorí náà, òun ni yóo jẹ́ ẹlẹ́rìí fun yín, kí ẹ má baà hùwà aiṣododo sí Ọlọrun yín.”

28. Joṣua bá pàṣẹ pé kí àwọn eniyan náà máa lọ, kí olukuluku pada sí orí ilẹ̀ rẹ̀.

29. Lẹ́yìn náà, nígbà tó yá, Joṣua ọmọ Nuni, iranṣẹ OLUWA kú nígbà tí ó di ẹni aadọfa (110) ọdún.

30. Wọ́n bá sin ín sórí ilẹ̀ rẹ̀ ní Timnati Sera, tí ó wà ní agbègbè olókè Efuraimu, ní apá ìhà àríwá Gaaṣi.

31. Àwọn ọmọ Israẹli sin OLUWA ní gbogbo àkókò tí Joṣua fi wà láàyè, ati ní àkókò àwọn àgbààgbà tí wọ́n ṣẹ́kù lẹ́yìn Joṣua, tí wọ́n mọ gbogbo ohun tí OLUWA ṣe fún Israẹli.

32. Àwọn ọmọ Israẹli sin egungun Josẹfu tí wọ́n gbé wá láti ilẹ̀ Ijipti sí Ṣekemu, lórí ilẹ̀ tí Jakọbu fi ọgọrun-un fadaka rà lọ́wọ́ àwọn ọmọ Hamori, tíí ṣe baba Ṣekemu, ilẹ̀ náà sì di àjogúnbá fún arọmọdọmọ Josẹfu.

33. Nígbà tí ó yá, Eleasari, ọmọ Aaroni kú; wọ́n sì sin ín sí Gibea, ìlú Finehasi, ọmọ rẹ̀, tí ó wà ní agbègbè olókè Efuraimu.

Ka pipe ipin Joṣua 24