Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joṣua 23:2-6 BIBELI MIMỌ (BM)

2. ó bá pe gbogbo àwọn ọmọ Israẹli jọ, àwọn àgbààgbà, ati àwọn olórí, àwọn onídàájọ́, ati àwọn alákòóso, ó wí fún wọn pé, “Mo ti di àgbàlagbà, ogbó sì ti dé sí mi;

3. ẹ̀yin náà ti rí ohun tí OLUWA Ọlọrun yín ti ṣe sí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi nítorí yín, ati pé OLUWA Ọlọrun yín ni ó jà fun yín.

4. Ẹ wò ó! Gbogbo ilẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè yòókù tí a kò tíì ṣẹgun, ati gbogbo àwọn tí a ti ṣẹgun ni mo ti pín fun yín gẹ́gẹ́ bí ogún yín, ohun tí ó bẹ̀rẹ̀ láti odò Jọdani, títí dé Òkun Mẹditarenia ní apá ìwọ̀ oòrùn,

5. OLUWA Ọlọrun yín yóo máa tì wọ́n sẹ́yìn fun yín, yóo máa lé wọn kúrò níwájú yín, ẹ óo sì gba ilẹ̀ wọn bí OLUWA Ọlọrun yín ti ṣèlérí fun yín.

6. Nítorí náà, ẹ dúró ṣinṣin kí ẹ sì máa ṣe gbogbo nǹkan tí a kọ sinu ìwé òfin Mose. Ẹ kò gbọdọ̀ yẹ ẹsẹ̀ kúrò ninu wọn sí ọ̀tún tabi sí òsì,

Ka pipe ipin Joṣua 23