Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joṣua 22:1-8 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Lẹ́yìn náà, Joṣua pe àwọn ẹ̀yà Reubẹni ati ẹ̀yà Gadi ati ìdajì ẹ̀yà Manase,

2. ó wí fún wọn pé, “Gbogbo ohun tí Mose, iranṣẹ OLUWA pa láṣẹ fun yín ni ẹ ti ṣe; ẹ sì ti ṣe gbogbo ohun tí èmi náà pa láṣẹ fun yín.

3. Ẹ kò kọ àwọn arakunrin yín sílẹ̀ láti ọjọ́ yìí wá títí di òní, ṣugbọn ẹ fara balẹ̀, ẹ sì ti ń pa gbogbo àṣẹ OLUWA Ọlọrun yín mọ́.

4. Nisinsinyii, OLUWA Ọlọrun yín ti fún àwọn arakunrin yín ní ìsinmi gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ìlérí fún wọn; nítorí náà, ẹ pada lọ sí ilẹ̀ yín, níbi tí ohun ìní yín wà, àní ilẹ̀ tí Mose iranṣẹ OLUWA fun yín ní òdìkejì odò Jọdani.

5. Ẹ máa ranti lemọ́lemọ́ láti máa pa gbogbo òfin tí Mose iranṣẹ OLUWA fun yín mọ́, pé kí ẹ fẹ́ràn OLUWA Ọlọrun yín, kí ẹ sì máa rìn ní ọ̀nà rẹ̀, ẹ máa pa gbogbo òfin rẹ̀ mọ́, ẹ súnmọ́ ọn, kí ẹ sì máa sìn ín tọkàntọkàn.”

6. Joṣua bá súre fún wọn, lẹ́yìn náà, ó ní kí wọ́n pada lọ sí ilẹ̀ wọn, wọ́n sì pada lọ.

7. Mose ti kọ́kọ́ fún ìdajì ẹ̀yà Manase ní ilẹ̀ ní Baṣani; Joṣua sì fún ìdajì yòókù ní ilẹ̀ ní ẹ̀gbẹ́ ti àwọn arakunrin wọn, ní ìwọ̀ oòrùn odò Jọdani. Nígbà tí Joṣua rán wọn pada lọ sí ilé wọn, tí ó sì súre fún wọn, ó wí fún wọn pé,

8. “Ẹ máa kó ọpọlọpọ dúkìá pada lọ sí ilé yín, ati ọpọlọpọ ẹran ọ̀sìn, fadaka, wúrà, idẹ, irin, ati ọpọlọpọ aṣọ. Ẹ pín ninu ìkógun tí ẹ kó lọ́dọ̀ àwọn ọ̀tá yín fún àwọn arakunrin yín.”

Ka pipe ipin Joṣua 22