Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joṣua 20:1-6 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Lẹ́yìn náà, OLUWA sọ fún Joṣua pé,

2. “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé kí wọ́n yan àwọn ìlú ààbò tí mo bá Mose sọ nípa rẹ̀, pé kí ó sọ fun yín.

3. Kí ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣèèṣì pa eniyan lè sá lọ sibẹ. Ibẹ̀ ni yóo jẹ́ ibi ààbò fun yín tí ọwọ́ ẹni tí ń gbẹ̀san ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ kò fi ní máa tẹ̀ yín.

4. Kí ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣèèṣì pa eniyan sá lọ sí ọ̀kan ninu àwọn ìlú ọ̀hún, kí ó dúró ní ẹnubodè ìlú, kí ó sì ro ẹjọ́ fún àwọn àgbààgbà ibẹ̀. Wọn yóo mú un wọ inú ìlú lọ, wọn yóo fún un ní ibi tí yóo máa gbé, yóo sì wà ní ọ̀dọ̀ wọn.

5. Bí ẹni tí ń gbẹ̀san ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ bá ń lé e bọ̀, wọn kò ní fi lé e lọ́wọ́, nítorí pé ó ṣèèṣì pa aládùúgbò rẹ̀ ni, kò sì ní ìkùnsínú sí i tẹ́lẹ̀.

6. Ìlú yìí ni yóo máa gbé títí tí àwọn ìgbìmọ̀ yóo fi ṣe ìdájọ́ rẹ̀, yóo máa gbé ibẹ̀ títí tí ẹni tí ó jẹ́ olórí alufaa ní àkókò náà yóo fi kú, lẹ́yìn náà ẹni tí ó ṣèèṣì pa eniyan yìí lè pada lọ sí ilé rẹ̀ ati sí ìlú rẹ̀ níbi tí ó ti sá wá.”

Ka pipe ipin Joṣua 20