Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joṣua 2:7-17 BIBELI MIMỌ (BM)

7. Àwọn tí ọba rán bá bẹ̀rẹ̀ sí lépa àwọn ọkunrin náà lọ ní ọ̀nà odò Jọdani, títí dé ibi tí ọ̀nà ti rékọjá odò náà, bí àwọn tí ọba rán ti jáde ní ìlú, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ti ìlẹ̀kùn odi ìlú náà.

8. Kí àwọn amí meji náà tó sùn, Rahabu gun òrùlé lọ bá wọn, ó ní,

9. “Mo mọ̀ pé OLUWA ti fi ilẹ̀ yìí lé e yín lọ́wọ́, jìnnìjìnnì yín ti bò wá, ẹ̀rù yín sì ti ń ba gbogbo àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ yìí.

10. Nítorí a ti gbọ́ bí OLUWA ti mú kí Òkun Pupa gbẹ níwájú yín nígbà tí ẹ jáde ní Ijipti, a sì ti gbọ́ ohun tí ẹ ṣe sí Sihoni ati Ogu, àwọn ọba ará Amori mejeeji tí wọ́n wà ní òkè odò Jọdani, bí ẹ ṣe pa wọ́n run patapata.

11. Bí a ti gbọ́ ni jìnnìjìnnì ti bò wá, ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn sì ti bá gbogbo eniyan nítorí yín, nítorí pé OLUWA Ọlọrun yín ni Ọlọrun ọ̀run ati ayé.

12. Nítorí náà, ẹ fi OLUWA búra fún mi nisinsinyii pé, bí mo ti ṣe yín lóore yìí, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin náà yóo ṣe ilé baba mi lóore, kí ẹ sì fún mi ní àmì tí ó dájú.

13. Kí ẹ dá baba mi ati ìyá mi sí, ati àwọn arakunrin mi, ati àwọn arabinrin mi, ati gbogbo àwọn eniyan wọn; ẹ má jẹ́ kí á kú.”

14. Àwọn ọkunrin náà bá dá a lóhùn pé, “Kí OLUWA gba ẹ̀mí wa bí a bá pa yín. Bí o kò bá ṣá ti sọ ohun tí a wá ṣe níhìn-ín fún ẹnikẹ́ni, a óo ṣe ọ́ dáradára, a óo sì jẹ́ olóòótọ́ sí ọ nígbà tí OLUWA bá fi ilẹ̀ náà lé wa lọ́wọ́.”

15. Ó bá fi okùn kan sọ̀ wọ́n kalẹ̀ láti ojú fèrèsé, nítorí pé àkọ́pọ̀ mọ́ odi ìlú ni wọ́n kọ́ ilé rẹ̀, inú odi yìí ni ó sì ń gbé.

16. Ó bá kìlọ̀ fún wọn pé, “Ẹ sá lọ sí orí òkè, kí àwọn tí wọ́n ń lépa yín má baà pàdé yín lójú ọ̀nà. Ẹ sá pamọ́ fún ọjọ́ mẹta, títí tí wọn óo fi pada dé. Lẹ́yìn náà, ẹ máa bá tiyín lọ.”

17. Àwọn ọkunrin náà sọ fún Rahabu pé, “A óo mú ìlérí tí o mú kí á fi ìbúra ṣe fún ọ ṣẹ.

Ka pipe ipin Joṣua 2