Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joṣua 19:27-32 BIBELI MIMỌ (BM)

27. Ààlà rẹ̀ wá yípo lọ sí apá ìlà oòrùn, títí dé Beti Dagoni, títí dé Sebuluni ati àfonífojì Ifitaeli ní apá àríwá Betemeki ati Neieli. Lẹ́yìn náà ó tún lọ ní apá ìhà àríwá náà títí dé Kabulu,

28. Eburoni, Rehobu, Hamoni, ati Kana, títí dé Sidoni Ńlá;

29. Lẹ́yìn náà, ààlà náà yípo lọ sí Rama; ó dé ìlú olódi ti Tire, lẹ́yìn náà, ó yípo lọ sí Hosa, ó sì pin sí etíkun. Ninu ilẹ̀ wọn ni Mahalabu, Akisibu;

30. Uma, Afeki, ati Rehobu wà, gbogbo ìlú ati ìletò wọn jẹ́ mejilelogun.

31. Àwọn ni ìlú ati ìletò tí ó wà ninu ilẹ̀ tí ó kan ẹ̀yà Aṣeri gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn.

32. Ilẹ̀ kẹfa tí wọ́n ṣẹ́ gègé lé lórí bọ́ sí ọwọ́ ẹ̀yà Nafutali,

Ka pipe ipin Joṣua 19