Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joṣua 15:18-29 BIBELI MIMỌ (BM)

18. Nígbà tí Akisa dé ọ̀dọ̀ ọkọ rẹ̀, ó rọ ọkọ rẹ̀ pé kí ó tọrọ ilẹ̀ kan lọ́wọ́ baba òun. Ní ọjọ́ kan, bí Akisa ti sọ̀kalẹ̀ ní orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, baba rẹ̀ bi í pé, “Kí ni ò ń fẹ́?”

19. Akisa dá baba rẹ̀ lóhùn pé, “Fún mi ní ẹ̀bùn, níwọ̀n ìgbà tí o ti fún mi ní ilẹ̀ Nẹgẹbu, fún mi ní àwọn orísun omi pẹlu.” Kalebu bá fún un ní àwọn orísun omi tí wọ́n wà lókè ati àwọn tí wọ́n wà ní ìsàlẹ̀.

20. Èyí ni ilẹ̀ ẹ̀yà Juda gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn,

21. àwọn ìlú tí ó jẹ́ tiwọn ní ìpẹ̀kun apá ìhà gúsù lẹ́bàá ààlà Edomu nìwọ̀nyí: Kabiseeli, Ederi, Jaguri,

22. Kina, Dimona, Adada,

23. Kedeṣi, Hasori, Itinani;

24. Sifi, Telemu, Bealoti;

25. Hasori Hadata, Kerioti Hesironi (tí a tún ń pè ní Hasori);

26. Amamu, Ṣema, Molada;

27. Hasari Gada, Heṣimoni, Betipeleti;

28. Hasari Ṣuali, Beeriṣeba, Bisiotaya;

29. Baala, Iimu, Esemu;

Ka pipe ipin Joṣua 15