Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joṣua 13:30-33 BIBELI MIMỌ (BM)

30. Ilẹ̀ tiwọn bẹ̀rẹ̀ láti Mahanaimu, títí dé gbogbo ilẹ̀ Baṣani, gbogbo ilẹ̀ ìjọba Ogu, ọba Baṣani, ati gbogbo àwọn ìlú Jairi tí ó wà ní Baṣani, gbogbo ìlú wọn jẹ́ ọgọta.

31. Ninu ilẹ̀ wọn ni ìdajì Gileadi wà ati Aṣitarotu ati Edirei, àwọn ìlú ńláńlá ilẹ̀ ìjọba Ogu, ọba Baṣani; Mose pín wọn fún àwọn ìdajì ìdílé Makiri, ọmọ Manase, gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn.

32. Àkọsílẹ̀ bí Mose ṣe pín ilẹ̀ tí ó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu ní òdìkejì Jọdani ní apá ìlà oòrùn Jẹriko nìyí.

33. Ṣugbọn Mose kò pín ilẹ̀ fún àwọn ẹ̀yà Lefi, OLUWA Ọlọrun Israẹli ni ìpín tiwọn, gẹ́gẹ́ bí ó ti wí fún wọn.

Ka pipe ipin Joṣua 13