Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joṣua 13:29-32 BIBELI MIMỌ (BM)

29. Mose fún ìdajì ẹ̀yà Manase ní ìpín tiwọn gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn.

30. Ilẹ̀ tiwọn bẹ̀rẹ̀ láti Mahanaimu, títí dé gbogbo ilẹ̀ Baṣani, gbogbo ilẹ̀ ìjọba Ogu, ọba Baṣani, ati gbogbo àwọn ìlú Jairi tí ó wà ní Baṣani, gbogbo ìlú wọn jẹ́ ọgọta.

31. Ninu ilẹ̀ wọn ni ìdajì Gileadi wà ati Aṣitarotu ati Edirei, àwọn ìlú ńláńlá ilẹ̀ ìjọba Ogu, ọba Baṣani; Mose pín wọn fún àwọn ìdajì ìdílé Makiri, ọmọ Manase, gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn.

32. Àkọsílẹ̀ bí Mose ṣe pín ilẹ̀ tí ó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu ní òdìkejì Jọdani ní apá ìlà oòrùn Jẹriko nìyí.

Ka pipe ipin Joṣua 13