Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jona 4:1-10 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ṣugbọn bí Ọlọrun ti ṣe yìí kò dùn mọ́ Jona ninu rárá, inú bí i.

2. Ó bá gbadura sí OLUWA, ó ní: “OLUWA, ṣebí ohun tí mo sọ láti ìbẹ̀rẹ̀ nìyí, nígbà tí mo wà ní orílẹ̀-èdè mi? Nítorí náà ni mo ṣe sa gbogbo ipá mi láti sálọ sí Taṣiṣi; nítorí mo mọ̀ pé Ọlọrun onífẹ̀ẹ́ ati aláàánú ni ọ́, o ní sùúrù, o kún fún ìfẹ́ tí kì í yẹ̀, ò sì máa yí ibi tí o bá ti pinnu láti ṣe pada.

3. Ǹjẹ́ nisinsinyii, OLUWA, mo bẹ̀ ọ́, gba ẹ̀mí mi, nítorí pé, ó sàn fún mi láti kú ju pé kí n wà láàyè lọ.”

4. OLUWA bá dá Jona lóhùn pé, “Ǹjẹ́ ó yẹ kí o bínú?”

5. Jona bá jáde kúrò láàrin ìlú náà, ó sì lọ jókòó sí ìhà ìlà oòrùn ìlú náà. Ó pa àtíbàbà kan sibẹ, ó jókòó ní ìbòòji lábẹ́ rẹ̀, ó ń retí ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí ìlú náà.

6. OLUWA bá rán ìtàkùn kan, ó fà á bo ibẹ̀, o sì ṣíji bo orí ibi tí Jona wà kí ó lè fún un ní ìtura ninu ìnira rẹ̀. Inú Jona dùn gidigidi nítorí ìtàkùn yìí.

7. Ṣugbọn Ọlọrun rán kòkòrò kan ní àárọ̀ ọjọ́ keji, ó jẹ ìtàkùn náà, ó sì rọ.

8. Nígbà tí oòrùn yọ, Ọlọrun mú kí afẹ́fẹ́ ìhà ìlà oòrùn fẹ́, oòrùn sì pa Jona tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi fẹ́rẹ̀ dákú. Ó sọ fún Ọlọrun pé kí ó gba ẹ̀mí òun. Ó ní, “Ó sàn kí n kú ju pé kí n wà láàyè lọ.”

9. Ọlọrun bá bi Jona pé, “Ǹjẹ́ o lẹ́tọ̀ọ́ láti bínú nítorí ìtàkùn yìí?” Jona dáhùn, ó ní: “Ó tọ́ kí n bínú títí dé ojú ikú.”

10. Nígbà náà ni OLUWA dá a lóhùn pé, “ìwọ ń káàánú ìtàkùn lásánlàsàn, tí o kò ṣiṣẹ́ fún, tí kì í sìí ṣe ìwọ ni o mú un dàgbà, àní ìtàkùn tí ó hù ní òru ọjọ́ kan, tí ó sì gbẹ ní ọjọ́ keji.

Ka pipe ipin Jona 4