Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joẹli 1:1-13 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Iṣẹ́ tí OLUWA rán Joẹli, ọmọ Petueli nìyí:

2. Ẹ gbọ́, ẹ̀yin àgbà,ẹ fetí sílẹ̀, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé ilẹ̀ yìí!Ǹjẹ́ irú ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ti ṣẹlẹ̀ rí ní àkókò yín,tabi ní àkókò àwọn baba yín?

3. Ẹ sọ fún àwọn ọmọ yín nípa rẹ̀,kí àwọn náà sọ fún àwọn ọmọ wọn,kí àwọn ọmọ wọn sì sọ fún àwọn ọmọ tiwọn náà.

4. Ohun tí eṣú wẹẹrẹ jẹ kù,ọ̀wọ́ àwọn eṣú ńláńlá jẹ ẹ́.Èyí tí ọ̀wọ́ àwọn eṣú ńláńlá jẹ kù,àwọn eṣú wẹẹrẹ mìíràn jẹ ẹ́,èyí tí àwọn eṣú wẹẹrẹ yìí jẹ kù,àwọn eṣú tí ń jẹ nǹkan run jẹ ẹ́ tán.

5. Ẹ jí lójú oorun, ẹ̀yin ọ̀mùtí,ẹ sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn,gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń mu waini,nítorí waini tuntun tí a já gbà kúrò lẹ́nu yín.

6. Orílẹ̀-èdè kan ti dojú kọ ilẹ̀ mi,wọ́n lágbára, wọ́n pọ̀, wọn kò sì lóǹkà;eyín wọn dàbí ti kinniun.Ọ̀gàn wọn sì dàbí ti abo kinniun.

7. Wọ́n ti run ọgbà àjàrà mi,wọ́n ti já àwọn ẹ̀ka igi ọ̀pọ̀tọ́ mi,wọ́n ti bó gbogbo èèpo ara rẹ̀,wọ́n ti wó o lulẹ̀,àwọn ẹ̀ka rẹ̀ sì ti di funfun.

8. Ẹ sọkún bí ọmọge tí ó fi aṣọ ọ̀fọ̀ bora,nítorí ikú àfẹ́sọ́nà ìgbà èwe rẹ̀.

9. A ti dáwọ́ ẹbọ ohun jíjẹ ati ti ohun mímu dúró ní ilé OLUWA,àwọn alufaa tíí ṣe iranṣẹ OLUWA ń ṣọ̀fọ̀.

10. Ilẹ̀ ti gbẹ, ó ń ṣọ̀fọ̀,nítorí a ti run ọkà, àjàrà ti tán, epo olifi sì ń tán lọ.

11. Ẹ banújẹ́, ẹ̀yin àgbẹ̀,ẹ sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn ẹ̀yin tí ẹ̀ ń tọ́jú ọgbà àjàrà,nítorí ọkà alikama ati ọkà baali,ati nítorí pé ohun ọ̀gbìn ti ṣègbé.

12. Èso àjàrà ti rọ,igi ọ̀pọ̀tọ́ sì ti ń gbẹ.Igi pomegiranate, igi ọ̀pẹ ati igi ápù, ati gbogbo àwọn igi eléso ti gbẹ,inú ọmọ eniyan kò sì dùn mọ́.

13. Ẹ wọ aṣọ ọ̀fọ̀, kí ẹ sì sọkún, ẹ̀yin alufaa,ẹ sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn,ẹ̀yin tí ẹ̀ ǹ ṣiṣẹ́ ní ibi pẹpẹ ìrúbọ.Ẹ̀yin òjíṣẹ́ Ọlọrun mi, ẹ wọlé,kí ẹ sì fi aṣọ ọ̀fọ̀ bora sùn,nítorí a ti dáwọ́ ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu dúró ní ilé Ọlọrun yín.

Ka pipe ipin Joẹli 1