Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 32:11-18 BIBELI MIMỌ (BM)

11. “Mo farabalẹ̀ nígbà tí ẹ̀yin ń sọ̀rọ̀,mo fetí sí ọ̀rọ̀ ọgbọ́n yín,nígbà tí ẹ̀ ń ronú ohun tí ẹ fẹ́ sọ,

12. Mo farabalẹ̀ fun yín,ṣugbọn kò sí ẹnikẹ́ni ninu yín tí ó lè ko Jobu lójú,kí ó sì fi àṣìṣe rẹ̀ hàn án,tabi kí ó fún un lésì àwọn àwíjàre rẹ̀.

13. Ẹ ṣọ́ra, kí ẹ má baà wí pé, ‘A ti di ọlọ́gbọ́n,Ọlọrun ló lè ṣe ìdájọ́ rẹ̀, kì í ṣe eniyan.’

14. Èmi kọ́ ni Jobu ń bá wí, ẹ̀yin ni,n kò sì ní dá a lóhùn bí ẹ ṣe dá a lóhùn.

15. “Ọkàn wọn dàrú, wọn kò sì lè fèsì mọ́,bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní ohun kan láti sọ.

16. Ṣé kí n dúró,nítorí pé wọ́n dúró láìfèsì?

17. Èmi náà óo fèsì lé e,n óo sì sọ èrò ọkàn tèmi.

18. Mo ní ọ̀rọ̀ pupọ láti sọ,Ṣugbọn ẹ̀mí tí ó wà ninu mi ló ń kó mi ní ìjánu.

Ka pipe ipin Jobu 32