Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 14:4-14 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Ta ló lè mú ohun mímọ́ jádeláti inú ohun tí kò mọ́?Kò sí ẹni náà.

5. Níwọ̀n ìgbà tí a ti dá ọjọ́ fún un,tí o mọ iye oṣù rẹ̀,tí o sì ti pa ààlà tí kò lè rékọjá.

6. Mú ojú rẹ kúrò lára rẹ̀, kí ó lè sinmi,kí ó sì lè gbádùn ọjọ́ ayé rẹ̀ bí alágbàṣe.

7. “Nítorí pé ìrètí ń bẹ fún igi tí wọn gé,yóo tún pada rúwé,ẹ̀ka rẹ̀ kò sì ní ṣe aláìsọ.

8. Bí gbòǹgbò rẹ̀ tilẹ̀ di ògbólógbòó ninu ilẹ̀,tí kùkùté rẹ̀ sì kú,

9. bí ó bá ti gbóòórùn omi, yóo sọ,yóo sì yọ ẹ̀ka bí ọ̀dọ́ irúgbìn.

10. Ṣugbọn bí eniyan bá kú, a óo tẹ́ ẹ sinu ibojì,bí ó bá ti gbẹ́mìí mì, ó di aláìsí.

11. Bí adágún omi tíí gbẹ,ati bí odò tíí ṣàn lọ, tí sìí gbẹ,

12. bẹ́ẹ̀ ni eniyan ṣe é sùn,tí kì í sìí jí mọ́,títí tí ọ̀run yóo fi kọjá lọ, kò ní jí,tabi kí ó tilẹ̀ rúnra láti ojú oorun.

13. Ìbá sàn kí o fi mí pamọ́ sinu ibojì,kí o pa mí mọ́ títí inú rẹ yóo fi rọ̀,ò bá dá àkókò fún mi, kí o sì ranti mi.

14. Bí eniyan bá kú, ǹjẹ́ yóo tún jí mọ́?N óo dúró ní gbogbo ọjọ́ làálàá mi,n óo máa retí, títí ọjọ́ ìdáǹdè mi yóo fi dé.

Ka pipe ipin Jobu 14