Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 9:7-22 BIBELI MIMỌ (BM)

7. Nítorí náà, ó ní:“Wò ó! N óo fọ̀ wọ́n mọ́,n óo dán wọn wò.Àbí, kí ni kí n tún ṣe fún àwọn eniyan yìí?

8. Ahọ́n wọn dàbí ọfà apanirun,wọ́n ń sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn.Olukuluku ń sọ̀rọ̀ alaafia jáde lẹ́nu fún aládùúgbò rẹ̀,ṣugbọn ète ikú ni ó ń pa sí i ninu ọkàn rẹ̀.

9. Ṣé n kò wá ní jẹ wọ́n níyà fún àwọn nǹkan tí wọ́n ṣe wọnyi?Àbí n kò ní gbẹ̀san ara mi lára irú orílẹ̀-èdè yìí?”

10. Mo ní, “Gbé ẹnu sókè kí o sọkún nítorí àwọn òkè ńlá,sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn nítorí àwọn pápá inú aṣálẹ̀,nítorí gbogbo wọn ti di ahoro, láìsí ẹnìkan tí yóo la ààrin wọn kọjá.A kò ní gbọ́ ohùn ẹran ọ̀sìn níbẹ̀.Ati ẹyẹ, ati ẹranko, gbogbo wọn ti sá lọ.”

11. OLUWA ní, “N óo sọ Jerusalẹmu di àlàpà ati ibùgbé ajáko.N óo sọ àwọn ìlú Juda di ahoroẹnikẹ́ni kò ní gbé inú wọn mọ́.Èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

12. Mo bá bèèrè pé, “Ta ni ẹni tí ó gbọ́n, tí òye nǹkan yìí yé? Ta ni OLUWA ti bá sọ̀rọ̀, kí ó kéde rẹ̀? Kí ló dé tí ilẹ̀ náà fi parun, tí ó sì dàbí aṣálẹ̀ tóbẹ́ẹ̀, tí ẹnikẹ́ni kò fi gba ibẹ̀ kọjá?”

13. OLUWA bá dáhùn, ó ní, “Nítorí pé wọ́n kọ òfin tí mo gbékalẹ̀ fún wọn sílẹ̀, wọn kò gbọ́ràn sí mi lẹ́nu, wọn kò sì ṣe gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ mi,

14. ṣugbọn wọ́n ń fi agídí ṣe ìfẹ́ ọkàn wọn, wọ́n ń bọ àwọn oriṣa Baali, bí àwọn baba wọn ti kọ́ wọn.

15. Nítorí náà, n óo fún wọn ní igi tí ó korò jẹ, n óo sì fún wọn ní omi tí ó ní májèlé mu. Èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

16. N óo fọ́n wọn ká sí ààrin àwọn orílẹ̀-èdè tí àwọn ati àwọn baba ńlá wọn kò mọ̀, n óo sì jẹ́ kí àwọn ọ̀tá yọ idà tẹ̀lé wọn títí tí n óo fi pa wọ́n run.”

17. OLUWA àwọn ọmọ ogun ní:“Ẹ ronú sí ọ̀rọ̀ yìí kí ẹ pe àwọn obinrin tíí máa ń ṣọ̀fọ̀ wá,ẹ ranṣẹ pe àwọn obinrin tí wọ́n mọ ẹkún sun dáradára;

18. kí wọ́n wá kíá,kí wọ́n wá máa sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn lé wa lórí,kí omi sì máa dà lójú wa pòròpòrò.

19. Nítorí a gbọ́ tí ẹkún sọ ní Sioni,wọ́n ń ké pé, ‘A gbé!Ìtìjú ńlá dé bá wa,a níláti kó jáde nílé,nítorí pé àwọn ọ̀tá ti wó ilé wa.’ ”

20. Mo ní, “Ẹ̀yin obinrin, ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA wí,ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀.Ẹ kọ́ àwọn ọmọ yín obinrin ní ẹkún sísun,kí ẹ sì kọ́ aládùúgbò yín ní orin arò.

21. Nítorí ikú ti dé ojú fèrèsé wa,ó ti wọ ààfin wa.Ikú ń pa àwọn ọmọde nígboro,ati àwọn ọdọmọkunrin ní gbàgede.”

22. Sọ wí pé,“Òkú eniyan yóo sùn lọ nílẹ̀ bí ìgbọ̀nsẹ̀ lórí pápá tí ó tẹ́jú,ati bíi ìtí ọkà lẹ́yìn àwọn tí wọn ń kórè ọkà,kò sì ní sí ẹni tí yóo kó wọn jọ. OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.”

Ka pipe ipin Jeremaya 9